Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Anbiyā’   Ayah:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلَّا نُوحِيٓ إِلَيۡهِ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعۡبُدُونِ
A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.”[1]
[1] Āyah yìí ti fi hàn kedere pé, ìpèpè gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ni "at-taohīd", kì í ṣe "aṣṣirk".
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَلَدٗاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۚ بَلۡ عِبَادٞ مُّكۡرَمُونَ
Wọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé sọ ẹnì kan di ọmọ (nínú àwọn mọlāikah Rẹ̀).” Mímọ́ ni fún Un - Kò rí bẹ́ẹ̀; ẹrúsìn alápọ̀n-ọ́nlé ni wọ́n.
Arabic explanations of the Qur’an:
لَا يَسۡبِقُونَهُۥ بِٱلۡقَوۡلِ وَهُم بِأَمۡرِهِۦ يَعۡمَلُونَ
Wọn kì í ṣíwájú Allāhu sọ ọ̀rọ̀. Wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَلَا يَشۡفَعُونَ إِلَّا لِمَنِ ٱرۡتَضَىٰ وَهُم مِّنۡ خَشۡيَتِهِۦ مُشۡفِقُونَ
(Allāhu) mọ ohun tó ń bẹ níwájú wọn àti ohun tó ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì níí ṣìpẹ̀ (ẹnì kan) àfi ẹni tí (Allāhu) bá yọ́nú sí. Wọ́n tún ń páyà fún ìbẹ̀rù Rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ وَمَن يَقُلۡ مِنۡهُمۡ إِنِّيٓ إِلَٰهٞ مِّن دُونِهِۦ فَذَٰلِكَ نَجۡزِيهِ جَهَنَّمَۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلظَّٰلِمِينَ
Àti pé ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá wí pé: “Dájúdájú èmi ni ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀.” Nítorí ìyẹn sì ni A óò fi san án ní ẹ̀san iná Jahanamọ. Báyẹn sì ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَوَلَمۡ يَرَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ كَانَتَا رَتۡقٗا فَفَتَقۡنَٰهُمَاۖ وَجَعَلۡنَا مِنَ ٱلۡمَآءِ كُلَّ شَيۡءٍ حَيٍّۚ أَفَلَا يُؤۡمِنُونَ
Ṣé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò wòye pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti ara omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni?[1]
[1] Āyah yìí ń sọ pàtàkì omi fún ìṣẹ̀mí abẹ̀mí.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَجَعَلۡنَا فِي ٱلۡأَرۡضِ رَوَٰسِيَ أَن تَمِيدَ بِهِمۡ وَجَعَلۡنَا فِيهَا فِجَاجٗا سُبُلٗا لَّعَلَّهُمۡ يَهۡتَدُونَ
A sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. A sì fi àwọn ọ̀nà fífẹ̀ sáààrin àwọn àpáta nítorí kí wọ́n lè rí ọ̀nà tọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَجَعَلۡنَا ٱلسَّمَآءَ سَقۡفٗا مَّحۡفُوظٗاۖ وَهُمۡ عَنۡ ءَايَٰتِهَا مُعۡرِضُونَ
A tún ṣe sánmọ̀ ní àjà tí wọ́n ń ṣọ́ (níbi jíjábọ́). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi àwọn àmì rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ فِي فَلَكٖ يَسۡبَحُونَ
Òun ni Ẹni tí Ó dá òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn àti òṣùpá. Ìkọ̀ọ̀kan (òòrùn àti òṣùpá) wà ní òpópónà roboto tó ń tọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَا جَعَلۡنَا لِبَشَرٖ مِّن قَبۡلِكَ ٱلۡخُلۡدَۖ أَفَإِيْن مِّتَّ فَهُمُ ٱلۡخَٰلِدُونَ
A kò ṣe bíbẹ gbére fún abara kan ṣíwájú rẹ. Ǹjẹ́ tí o bá kú, àwọn sì ni olùṣegbére bí?[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah kẹjọ.
Arabic explanations of the Qur’an:
كُلُّ نَفۡسٖ ذَآئِقَةُ ٱلۡمَوۡتِۗ وَنَبۡلُوكُم بِٱلشَّرِّ وَٱلۡخَيۡرِ فِتۡنَةٗۖ وَإِلَيۡنَا تُرۡجَعُونَ
Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A sì máa fi aburú àti rere ṣàdánwò fún yín. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Anbiyā’
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close