Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Tā-ha   Ayah:
وَلَقَدۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَسۡرِ بِعِبَادِي فَٱضۡرِبۡ لَهُمۡ طَرِيقٗا فِي ٱلۡبَحۡرِ يَبَسٗا لَّا تَخَٰفُ دَرَكٗا وَلَا تَخۡشَىٰ
Àti pé dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā báyìí pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru. Fi (ọ̀pá rẹ) na omi fún wọn (kí ó di) ojú ọ̀nà gbígbẹ kan nínú omi òkun.[1] O ò níí bẹ̀rù àlébá, o ò sì níí páyà (ìtẹ̀rì sínú omi òkun).”
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:50.
Arabic explanations of the Qur’an:
فَأَتۡبَعَهُمۡ فِرۡعَوۡنُ بِجُنُودِهِۦ فَغَشِيَهُم مِّنَ ٱلۡيَمِّ مَا غَشِيَهُمۡ
Fir‘aon sì tẹ̀lé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ohun tí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru nínú odò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَأَضَلَّ فِرۡعَوۡنُ قَوۡمَهُۥ وَمَا هَدَىٰ
Fir‘aon ṣi àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà; kò sì fi wọ́n mọ̀nà.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ قَدۡ أَنجَيۡنَٰكُم مِّنۡ عَدُوِّكُمۡ وَوَٰعَدۡنَٰكُمۡ جَانِبَ ٱلطُّورِ ٱلۡأَيۡمَنَ وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰ
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú A ti gbà yín là lọ́wọ́ ọ̀tá yín. A sì ṣe àdéhùn fún yín (pé kí Ànábì Mūsā wá, kí Á bá a sọ̀rọ̀ tààrà) ní ẹ̀gbẹ́ àpáta ní ọwọ́ ọ̀tún[1] (Ànábì Mūsā láààrin àpáta àti àfonífojì[2] ní ìwọ̀ òòrùn[3]). A sì sọ ohun mímu mọnu àti ohun jíjẹ salwā kalẹ̀ fún yín.[4]
[1] Ìyẹn ni pé, ìjúwe àpáta ibi tí Allāhu - tó ga jùlọ - ti bá Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - sọ̀rọ̀ tààrà nìyí, ó gbé àpáta sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àfonífojì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀ ní àgbègbè ìwọ̀-òòrùn ìlú náà. [2] Sūrah al-Ƙọsọs; 28:30 [3] Sūrah al-Ƙọsọs; 28:40 [4] Ìyẹn ni oúnjẹ wọn lórí ìrìn àrìnnù ológójì ọdún. Ẹ wo sūrah al-Mọ̄’idah 5:26.
Arabic explanations of the Qur’an:
كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ وَلَا تَطۡغَوۡاْ فِيهِ فَيَحِلَّ عَلَيۡكُمۡ غَضَبِيۖ وَمَن يَحۡلِلۡ عَلَيۡهِ غَضَبِي فَقَدۡ هَوَىٰ
Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pa lésè fún yín. Ẹ má sì kọjá ẹnu ààlà nínú rẹ̀ nítorí kí ìbínú Mi má baà kò le yín lórí. Ẹnikẹ́ni tí ìbínú Mi bá sì kò lé lórí, dájúdájú ó ti jábọ́ (sínú ìparun).
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِنِّي لَغَفَّارٞ لِّمَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا ثُمَّ ٱهۡتَدَىٰ
Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà tí ó tún tẹ̀lé ìmọ̀nà.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ وَمَآ أَعۡجَلَكَ عَن قَوۡمِكَ يَٰمُوسَىٰ
Kí ni ó mú ọ kánjú ya àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, Mūsā?
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ هُمۡ أُوْلَآءِ عَلَىٰٓ أَثَرِي وَعَجِلۡتُ إِلَيۡكَ رَبِّ لِتَرۡضَىٰ
Ó sọ pé: “Àwọn nìwọ̀nyí tí wọ́n ń tọ orípa mi bọ̀ (lẹ́yìn mi). Èmi sì kánjú wá sọ́dọ̀ Rẹ nítorí kí O lè yọ́nú sí mi ni, Olúwa mi.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ فَإِنَّا قَدۡ فَتَنَّا قَوۡمَكَ مِنۢ بَعۡدِكَ وَأَضَلَّهُمُ ٱلسَّامِرِيُّ
(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Àwa ti dán ìjọ rẹ wò lẹ́yìn rẹ. Àti pé Sāmiriy ṣì wọ́n lọ́nà.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَرَجَعَ مُوسَىٰٓ إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ غَضۡبَٰنَ أَسِفٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ أَلَمۡ يَعِدۡكُمۡ رَبُّكُمۡ وَعۡدًا حَسَنًاۚ أَفَطَالَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡعَهۡدُ أَمۡ أَرَدتُّمۡ أَن يَحِلَّ عَلَيۡكُمۡ غَضَبٞ مِّن رَّبِّكُمۡ فَأَخۡلَفۡتُم مَّوۡعِدِي
(Ànábì) Mūsā sì padà sọ́dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé Olúwa yín kò ti ba yín ṣe àdéhùn dáadáa ni? Ṣé àdéhùn ti pẹ́ jù lójú yín ni tàbí ẹ fẹ́ kí ìbínú kò le yín lórí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ẹ fi yapa àdéhùn mi?”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ مَآ أَخۡلَفۡنَا مَوۡعِدَكَ بِمَلۡكِنَا وَلَٰكِنَّا حُمِّلۡنَآ أَوۡزَارٗا مِّن زِينَةِ ٱلۡقَوۡمِ فَقَذَفۡنَٰهَا فَكَذَٰلِكَ أَلۡقَى ٱلسَّامِرِيُّ
Wọ́n wí pé: “Àwa kò fínnúfíndọ̀ yapa àdéhùn fúnra wa, ṣùgbọ́n wọ́n di ẹrù ọ̀ṣọ́ àwọn ènìyàn (Misrọ) rù wá lọ́rùn. A sì jù ú sínú iná (pẹ̀lú àṣẹ Sāmiriyy). Báyẹn náà sì ni Sāmiriyy ṣe ju tirẹ̀.”
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Tā-ha
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close