Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (89) Surah: Al-Baqarah
وَلَمَّا جَآءَهُمۡ كِتَٰبٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٞ لِّمَا مَعَهُمۡ وَكَانُواْ مِن قَبۡلُ يَسۡتَفۡتِحُونَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَلَمَّا جَآءَهُم مَّا عَرَفُواْ كَفَرُواْ بِهِۦۚ فَلَعۡنَةُ ٱللَّهِ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Nígbà tí Tírà kan sì dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ń fi ìdí òdodo múlẹ̀ nípa ohun tí ó wà pẹ̀lú wọn (ìyẹn tírà Taorāt), bẹ́ẹ̀ sì ni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti ń tọrọ ìṣẹ́gun lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àmọ́ nígbà tí ohun tí wọ́n nímọ̀ nípa rẹ̀ dé bá wọn, wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn aláìgbàgbọ́.[1]
[1] Ìyẹn ni pé, àwọn yẹ̀húdí, ṣíwájú kí Allāhu tó gbé Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dìde, wọ́n máa ń sọ fún àwọn ọ̀sẹbọ Lárúbáwá pé, “Ẹ jẹ́ tètè gba Allāhu gbọ́ ní òdodo bí bẹ́ẹ̀ kọ nígbà tí òpin Òjíṣẹ́ náà bá dé, àwọn àti òun máa parapọ̀ le yín lórí.” Àmọ́ nígbà tí òpin Òjíṣẹ́ náà - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dé, àwọn gan-an náà gbógun tì í nítorí pé, gbogbo èrò-ọkàn wọn ni pé, nínú ìran ọmọ Isrọ̄’īl ni òpin Òjíṣẹ́ náà máa ti wá. Àmọ́ nínú ìran Lárúbáwá ni Allāhu ti gbé òpin Òjíṣẹ́ náà dìde.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (89) Surah: Al-Baqarah
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close