Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (114) Surah: Al-Baqarah
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن مَّنَعَ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ أَن يُذۡكَرَ فِيهَا ٱسۡمُهُۥ وَسَعَىٰ فِي خَرَابِهَآۚ أُوْلَٰٓئِكَ مَا كَانَ لَهُمۡ أَن يَدۡخُلُوهَآ إِلَّا خَآئِفِينَۚ لَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Àti pé kò sí ẹni tó ṣàbòsí tó ẹni tí ó ṣe àwọn mọ́sálásí Allāhu ní èèwọ̀ láti ṣèrántí orúkọ Allāhu nínú rẹ̀, tí ó tún ṣiṣẹ́ lórí ìparun àwọn mọ́sálásí náà?[1] Àwọn wọ̀nyẹn, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti wọ inú rẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Àbùkù ń bẹ fún wọn n’ílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
[1] Àwọn onisūfī lérò pé āyah yìí ń ṣe é ní èèwọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti lé àwọn kúrò nínú mọ́sálásì tàbí láti kọ̀ fún wọn láti ṣe wiridi wọn àti waṭḥīfah wọn nínú mọ́sálásí. Rárá o. Āyah yìí kò gba bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹni tí kò jẹ́ kí àwa mùsùlùmí ṣe ìjọ́sìn tó tọ sunnah nínú mọ́sálásí ni Allāhu pè ní alábòsí jùlọ nínú āyah yìí, kì í ṣe ẹni tí ó kọ aburú àti bidiah ṣíṣe nínú àwọn mọ́sálásí. Ọ̀nà tí àwọn oníwírìdí ń gbà ṣe ìrántí Allāhu kò tọ sunnah rárá. Dandan sì ni fún wa láti lé wọn kúrò nínú mọ́sálásí Allāhu. “Zāwiyah” ni wọ́n máa ń kọ́ fún wírìdí bid‘ah, kì í ṣe mọ́sálásí.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (114) Surah: Al-Baqarah
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close