Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Baqarah   Ayah:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ سَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ ءَأَنذَرۡتَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تُنذِرۡهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn, wọn kò níí gbàgbọ́.[1]
[1] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kádàrá wọn lórí jíjẹ́ kèfèrí wọn kò níí yí padà. Àmọ́ ní ti àwọn tí kádàrá ìrònúpìwàdà máa borí wọn, ìkìlọ̀ máa sọ wọ́n di mùsulùmí.
Arabic explanations of the Qur’an:
خَتَمَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ وَعَلَىٰ سَمۡعِهِمۡۖ وَعَلَىٰٓ أَبۡصَٰرِهِمۡ غِشَٰوَةٞۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Allāhu fi èdídí dí ọkàn wọn àti ìgbọ́rọ̀ wọn. Èbìbò sì bo ìríran wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَقُولُ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَبِٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَمَا هُم بِمُؤۡمِنِينَ
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.” Wọn kì í sì ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Arabic explanations of the Qur’an:
يُخَٰدِعُونَ ٱللَّهَ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَمَا يَخۡدَعُونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمۡ وَمَا يَشۡعُرُونَ
(Wọ́n rò pé) àwọn ń tan Allāhu àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Wọn kò sì tan ẹnì kan bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura.
Arabic explanations of the Qur’an:
فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ فَزَادَهُمُ ٱللَّهُ مَرَضٗاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡذِبُونَ
Àrùn kan wà nínú ọkàn wọn[1], nítorí náà Allāhu ṣe àlékún àrùn (náà) fún wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn nítorí pé wọ́n ń parọ́.
[1] Àrùn iyèméjì àti ìṣojúméjì sí āyah al-Ƙur’ān.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ لَا تُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ قَالُوٓاْ إِنَّمَا نَحۡنُ مُصۡلِحُونَ
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Àwa kúkú ni alátùn-únṣe.”
Arabic explanations of the Qur’an:
أَلَآ إِنَّهُمۡ هُمُ ٱلۡمُفۡسِدُونَ وَلَٰكِن لَّا يَشۡعُرُونَ
Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òbìlẹ̀jẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò fura.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ ءَامِنُواْ كَمَآ ءَامَنَ ٱلنَّاسُ قَالُوٓاْ أَنُؤۡمِنُ كَمَآ ءَامَنَ ٱلسُّفَهَآءُۗ أَلَآ إِنَّهُمۡ هُمُ ٱلسُّفَهَآءُ وَلَٰكِن لَّا يَعۡلَمُونَ
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ ní òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe gbàgbọ́.” Wọ́n á wí pé: “Ṣé kí á gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn òmùgọ̀ ṣe gbàgbọ́ ni?” Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òmùgọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا لَقُواْ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَوۡاْ إِلَىٰ شَيَٰطِينِهِمۡ قَالُوٓاْ إِنَّا مَعَكُمۡ إِنَّمَا نَحۡنُ مُسۡتَهۡزِءُونَ
Nígbà tí wọ́n bá pàdé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì kù wọ́n ku àwọn (ẹni) ṣaetọ̄n wọn, wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwa ń bẹ pẹ̀lú yín, àwa kàn ń ṣe yẹ̀yẹ́ ni.”
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱللَّهُ يَسۡتَهۡزِئُ بِهِمۡ وَيَمُدُّهُمۡ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ
Allāhu máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sì máa mú wọn lékún sí i nínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.[1]
[1] Kì í ṣe gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ ni ó máa di orúkọ Rẹ̀ àfi èyí tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - sọllallāhu alaehi wa sallam - bá pè ní orúkọ Rẹ̀ àti ìròyìn Rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱشۡتَرَوُاْ ٱلضَّلَٰلَةَ بِٱلۡهُدَىٰ فَمَا رَبِحَت تِّجَٰرَتُهُمۡ وَمَا كَانُواْ مُهۡتَدِينَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà.[1] Nítorí náà, òkòwò wọn kò lérè, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.
[1] Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì - sọ pé, “Wọ́n mú ìṣìnà, wọ́n sì fi ìmọ̀nà sílẹ̀.” Tafsīr bun Kathīr.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Baqarah
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close