Check out the new design

قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى- ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل * - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

مەنالار تەرجىمىسى سۈرە: ياسىن   ئايەت:

Yaasiin

يسٓ
Yā sīn (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱلۡقُرۡءَانِ ٱلۡحَكِيمِ
(Allāhu) fi Al-Ƙur’ān tí ó kún fún ọgbọ́n búra.[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:1
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
(O) wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
تَنزِيلَ ٱلۡعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ
(Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أُنذِرَ ءَابَآؤُهُمۡ فَهُمۡ غَٰفِلُونَ
nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà).[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:46.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
لَقَدۡ حَقَّ ٱلۡقَوۡلُ عَلَىٰٓ أَكۡثَرِهِمۡ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّا جَعَلۡنَا فِيٓ أَعۡنَٰقِهِمۡ أَغۡلَٰلٗا فَهِيَ إِلَى ٱلۡأَذۡقَانِ فَهُم مُّقۡمَحُونَ
Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn (mọ́ ọwọ́ wọn). Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَجَعَلۡنَا مِنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ سَدّٗا وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ سَدّٗا فَأَغۡشَيۡنَٰهُمۡ فَهُمۡ لَا يُبۡصِرُونَ
Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَسَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ ءَأَنذَرۡتَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تُنذِرۡهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́.[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:6.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّمَا تُنذِرُ مَنِ ٱتَّبَعَ ٱلذِّكۡرَ وَخَشِيَ ٱلرَّحۡمَٰنَ بِٱلۡغَيۡبِۖ فَبَشِّرۡهُ بِمَغۡفِرَةٖ وَأَجۡرٖ كَرِيمٍ
Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìrántí (al-Ƙur’ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّا نَحۡنُ نُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَنَكۡتُبُ مَا قَدَّمُواْ وَءَاثَٰرَهُمۡۚ وَكُلَّ شَيۡءٍ أَحۡصَيۡنَٰهُ فِيٓ إِمَامٖ مُّبِينٖ
Dájúdájú Àwa l’À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan tó yanjú.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱضۡرِبۡ لَهُم مَّثَلًا أَصۡحَٰبَ ٱلۡقَرۡيَةِ إِذۡ جَآءَهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ
Fi àpèjúwe kan lélẹ̀ fún wọn nípa àwọn ará ìlú kan nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wá bá wọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِذۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهِمُ ٱثۡنَيۡنِ فَكَذَّبُوهُمَا فَعَزَّزۡنَا بِثَالِثٖ فَقَالُوٓاْ إِنَّآ إِلَيۡكُم مُّرۡسَلُونَ
(Rántí) nígbà tí A rán Òjíṣẹ́ méjì níṣẹ́ sí wọn. Wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. A sì fi ẹnì kẹta ró àwọn méjèèjì lágbára. Wọ́n sì sọ pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.”[1]
[1] Kíyè sí i! Ìtàn kan gbajúmọ̀ nínú àwọn tírà Tafsīr pé, àwọn mẹ́ta kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - tí ó rán níṣẹ́ lọ sí ìlú Antiok ni àwọn Òjíṣẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà. Àmọ́ nínú Tafsīr Ibn Kathīr, ó sọ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nítorí náà, má ṣe gbaralé ìtàn náà. Èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ni pé, wọ́n jẹ́ ara àwọn Òjíṣẹ́ tí Allāhu kò dárúkọ wọn fún Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ مَآ أَنتُمۡ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا وَمَآ أَنزَلَ ٱلرَّحۡمَٰنُ مِن شَيۡءٍ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا تَكۡذِبُونَ
Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú tiwa. Àjọkẹ́-ayé kò sì sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ رَبُّنَا يَعۡلَمُ إِنَّآ إِلَيۡكُمۡ لَمُرۡسَلُونَ
Wọ́n sọ pé: “Olúwa wa mọ̀ pé dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَا عَلَيۡنَآ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Kò sì sí ojúṣe kan fún wa bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُوٓاْ إِنَّا تَطَيَّرۡنَا بِكُمۡۖ لَئِن لَّمۡ تَنتَهُواْ لَنَرۡجُمَنَّكُمۡ وَلَيَمَسَّنَّكُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٞ
Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa rí àmì aburú lára yín. Tí ẹ kò bá jáwọ́ (níbi ìpèpè yín), dájúdájú a máa sọ yín lókò pa. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì jẹ yín láti ọ̀dọ̀ wa.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ طَٰٓئِرُكُم مَّعَكُمۡ أَئِن ذُكِّرۡتُمۚ بَلۡ أَنتُمۡ قَوۡمٞ مُّسۡرِفُونَ
Wọ́n sọ pé: “Àmì aburú yín ń bẹ pẹ̀lú yín. Ṣé nítorí pé wọ́n ṣe ìṣítí fún yín (l’ẹ fi rí àmì aburú lára wa)? Kò rí bẹ́ẹ̀! Ìjọ alákọyọ ni yín ni.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَجَآءَ مِنۡ أَقۡصَا ٱلۡمَدِينَةِ رَجُلٞ يَسۡعَىٰ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱتَّبِعُواْ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́ náà.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ٱتَّبِعُواْ مَن لَّا يَسۡـَٔلُكُمۡ أَجۡرٗا وَهُم مُّهۡتَدُونَ
Ẹ tẹ̀lé ẹni tí kò bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín. Olùmọ̀nà sì ni wọ́n.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَالِيَ لَآ أَعۡبُدُ ٱلَّذِي فَطَرَنِي وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Kí ni ó máa mú mi tí èmi kò fi níí jọ́sìn fún Ẹni tí Ó pilẹ̀ ẹ̀dá mi? Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ءَأَتَّخِذُ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةً إِن يُرِدۡنِ ٱلرَّحۡمَٰنُ بِضُرّٖ لَّا تُغۡنِ عَنِّي شَفَٰعَتُهُمۡ شَيۡـٔٗا وَلَا يُنقِذُونِ
Ṣé kí èmi sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́ fi ìnira kàn mí, ìṣìpẹ̀ wọn kò lè rọ̀ mí lọ́rọ̀ kiní kan, wọn kò sì lè gbà mí là.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنِّيٓ إِذٗا لَّفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ
(Bí èmi kò bá jọ́sìn fún Allāhu) nígbà náà dájúdájú mo ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنِّيٓ ءَامَنتُ بِرَبِّكُمۡ فَٱسۡمَعُونِ
Dájúdájú èmi gbàgbọ́ nínú Olúwa Ẹlẹ́dàá yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́ mi.” (Àwọn aláìgbàgbọ́ sì pa onígbàgbọ́ òdodo yìí.)
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قِيلَ ٱدۡخُلِ ٱلۡجَنَّةَۖ قَالَ يَٰلَيۡتَ قَوۡمِي يَعۡلَمُونَ
(Àwọn mọlāika) wọ́n sọ pé: “Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ó sọ pé: “(Ó mà ṣe o!) Àwọn ènìyàn mi ìbá ní ìmọ̀
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
بِمَا غَفَرَ لِي رَبِّي وَجَعَلَنِي مِنَ ٱلۡمُكۡرَمِينَ
nípa bí Olúwa mi ṣe foríjìn mí àti (bí) Ó ṣe fi mí sí ara àwọn alápọ̀n-ọ́nlé (wọn ìbá ronú pìwàdà).”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
۞ وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ مِنۢ بَعۡدِهِۦ مِن جُندٖ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا كُنَّا مُنزِلِينَ
A kò sọ ọmọ ogun kan kalẹ̀ lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí láti sánmọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. A kò sì sọ (mọlāika kan) kalẹ̀ (fún ìparun wọn).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِن كَانَتۡ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَإِذَا هُمۡ خَٰمِدُونَ
(Ìparun wọn) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan; nígbà náà ni wọ́n di òkú kalẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
يَٰحَسۡرَةً عَلَى ٱلۡعِبَادِۚ مَا يَأۡتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Àbámọ̀ mà ni fún àwọn ẹrúsìn náà (nígbà tí wọ́n bá fojú ara wọn rí Iná); òjíṣẹ́ kan kò níí wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَلَمۡ يَرَوۡاْ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ أَنَّهُمۡ إِلَيۡهِمۡ لَا يَرۡجِعُونَ
Ṣé wọn kò wòye pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? (Ṣé wọn kò wòye pé) dájúdájú wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ wọn mọ́ (nílé ayé) ni?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَإِن كُلّٞ لَّمَّا جَمِيعٞ لَّدَيۡنَا مُحۡضَرُونَ
Dájúdájú gbogbo wọn pátápátá sì ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sí ọ̀dọ̀ Wa.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَءَايَةٞ لَّهُمُ ٱلۡأَرۡضُ ٱلۡمَيۡتَةُ أَحۡيَيۡنَٰهَا وَأَخۡرَجۡنَا مِنۡهَا حَبّٗا فَمِنۡهُ يَأۡكُلُونَ
Àmì ni òkú ilẹ̀[1] jẹ́ fún wọn. A sọ ọ́ di ààyè. A sì mú èso jáde láti inú rẹ̀. Wọ́n sì ń jẹ nínú rẹ̀.
[1] Òkú ilẹ̀, ìyẹn ni ilẹ̀ tí ó ti di òkú tí kò lè hu irúgbìn kan kan.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَجَعَلۡنَا فِيهَا جَنَّٰتٖ مِّن نَّخِيلٖ وَأَعۡنَٰبٖ وَفَجَّرۡنَا فِيهَا مِنَ ٱلۡعُيُونِ
A tún ṣe àwọn ọgbà dàbínù àti àjàrà sórí ilẹ̀. A sì mú àwọn odò ìṣẹ́lẹ̀rú ṣàn láti inú rẹ̀
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
لِيَأۡكُلُواْ مِن ثَمَرِهِۦ وَمَا عَمِلَتۡهُ أَيۡدِيهِمۡۚ أَفَلَا يَشۡكُرُونَ
nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe![1] Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?
[1] Àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ Tafsīr túmọ̀ “mọ̄” tó jẹyọ nínú “وَمَا عَمِلَتْهُ أَيْدِيهِمْ ۖ” yìí sí “mọ̄-maosūlah’. Ìtúmọ̀ yìí l’a lò nínú āyah yìí. Ìtúmọ̀ náà sì dúró lé iṣẹ́ àgbẹ̀. Àwọn mìíràn sì túmọ̀ “mọ̄” yìí sí “mọ̄-nnāfiyah. Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbólóhùn náà máa túmọ̀ sí pé, “nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀, kì í sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?” Ìtúmọ̀ kejì dúró lé iṣẹ́ Allāhu lórí ìṣẹ̀dá n̄ǹkan oko. Ìyẹn ni pé, àdáyébá ni gbogbo èso. Kò sí èso kan tí ìṣẹ̀dá rẹ wá láti ọwọ́ àgbẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَزۡوَٰجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلۡأَرۡضُ وَمِنۡ أَنفُسِهِمۡ وَمِمَّا لَا يَعۡلَمُونَ
Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀.[1]
[1] Zaoj kò pọn dandan kí ó ní ìtúmọ̀ akọ àti abo nìkan. Oríṣiríṣi ni “zaoj”; akọ jẹ́ oríṣi kan, abo jẹ́ oríṣi kan, àwọ̀ jẹ oríṣi kan, èdè jẹ́ oríṣi kan, adùn jẹ́ oríṣi kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَءَايَةٞ لَّهُمُ ٱلَّيۡلُ نَسۡلَخُ مِنۡهُ ٱلنَّهَارَ فَإِذَا هُم مُّظۡلِمُونَ
Àmì kan ni òru jẹ́ fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn).[1]
[1] Kókó inú āyah yìí ni pé, òru l’ó ń ṣíwájú ọ̀sán nínú ọjọ́, bí àpẹ̀ẹrẹ, òru Jum'ah mọ́júmọ́ ọ̀sán Jum'ah, òru Sabt mọ́júmọ́ ọ̀sán Sabt. Nítorí náà, kò sí òru Àlàmísì mọ́júmọ́ ọ̀sán Jímọ̀. Kò sì sí òru Jímọ̀ mọ́júmọ́ Sabt.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱلشَّمۡسُ تَجۡرِي لِمُسۡتَقَرّٖ لَّهَاۚ ذَٰلِكَ تَقۡدِيرُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ
Àti pé òòrùn yóò máa rìn lọ sí àyè rẹ̀. Ìyẹn ni ètò (ti) Alágbára, Onímọ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱلۡقَمَرَ قَدَّرۡنَٰهُ مَنَازِلَ حَتَّىٰ عَادَ كَٱلۡعُرۡجُونِ ٱلۡقَدِيمِ
Òṣùpá náà, A ti ṣe òdíwọ̀n àwọn ibùsọ̀ fún un (tí ó ti ma máa tóbi sí i) títí ó máa fi padà dà bíi àran ọ̀pẹ tó ti pẹ́ (gbígbẹ).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
لَا ٱلشَّمۡسُ يَنۢبَغِي لَهَآ أَن تُدۡرِكَ ٱلۡقَمَرَ وَلَا ٱلَّيۡلُ سَابِقُ ٱلنَّهَارِۚ وَكُلّٞ فِي فَلَكٖ يَسۡبَحُونَ
Kò yẹ fún òòrùn láti lo àsìkò òṣùpá. Kò sì yẹ fún alẹ́ láti lo àsìkò ọ̀sán. Ìkọ̀ọ̀kan wà ní òpópónà róbótó tó ń tọ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَءَايَةٞ لَّهُمۡ أَنَّا حَمَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُمۡ فِي ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ
Àmì kan tún ni fún wọn pé, dájúdájú Àwa gbé àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn gun ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَخَلَقۡنَا لَهُم مِّن مِّثۡلِهِۦ مَا يَرۡكَبُونَ
A tún ṣẹ̀dá (òmíràn) fún wọn nínú irú rẹ̀ tí wọn yóò máa gún.[1]
[1] Ìyẹn ni pé n̄ǹkan ìgùn tí Allāhu dá fún wa, kò mọ ní ẹyọ kan. Àwọn n̄ǹkan ìgùn mìíràn tún wà bí àwọn ẹṣin, ràkúnmí, ìbaaka, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọkọ̀ inú òfurufú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَإِن نَّشَأۡ نُغۡرِقۡهُمۡ فَلَا صَرِيخَ لَهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنقَذُونَ
Tí A bá fẹ́ Àwa ìbá tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Kò níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn. Wọn kò sì níí gbà wọ́n là.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِلَّا رَحۡمَةٗ مِّنَّا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ
Àfi (kí Á fi) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa (yọ wọ́n jáde, kí A sì tún fún wọn ní) ìgbádùn ayé títí di ìgbà díẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّقُواْ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيكُمۡ وَمَا خَلۡفَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ
(Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín[1] àti ohun tó wà lẹ́yìn yín[2] nítorí kí A lè kẹ yín.”
[1] “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín”; ohun tí ó wà níwájú wọn ni àwọn àpẹ̀ẹrẹ irú ìyà àti ìparun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n pé ọ̀rọ̀ Allahu - Ọba Òdodo - ní irọ́ ṣíwájú wọn. [2] “àti ohun tó wà lẹ́yìn yín”; ohun tí ó wà lẹ́yìn wọn ni ìyà ọjọ́ Àjíǹde, ìyà Iná tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n pé ọ̀rọ̀ Allahu - Ọba Òdodo - ní irọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَا تَأۡتِيهِم مِّنۡ ءَايَةٖ مِّنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِمۡ إِلَّا كَانُواْ عَنۡهَا مُعۡرِضِينَ
Àti pé āyah kan nínú àwọn āyah Olúwa wọn kò níí wá bá wọn àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ أَنفِقُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنُطۡعِمُ مَن لَّوۡ يَشَآءُ ٱللَّهُ أَطۡعَمَهُۥٓ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Nígbà tí A bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín.”, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí fún àwọn tó gbàgbọ́ pé: “Ṣé kí á bọ́ ẹni tí (ó jẹ́ pé) Allāhu ìbá fẹ́ ìbá bọ́ ọ (àmọ́ kò bọ́ ọ. Àwa náà kò sì níí bá A bọ́ ọ)?” Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé (ẹ wà) nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
مَا يَنظُرُونَ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ تَأۡخُذُهُمۡ وَهُمۡ يَخِصِّمُونَ
Wọn kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa gbá wọn mú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àríyànjiyàn lọ́wọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ تَوۡصِيَةٗ وَلَآ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمۡ يَرۡجِعُونَ
Nígbà náà, wọn kò níí lè sọ àsọọ́lẹ̀ kan. Wọn kò sì níí lè padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَإِذَا هُم مِّنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ يَنسِلُونَ
Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا مَنۢ بَعَثَنَا مِن مَّرۡقَدِنَاۜۗ هَٰذَا مَا وَعَدَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَصَدَقَ ٱلۡمُرۡسَلُونَ
Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?” Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِن كَانَتۡ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَإِذَا هُمۡ جَمِيعٞ لَّدَيۡنَا مُحۡضَرُونَ
Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn wá sí ọ̀dọ̀ Wa.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَٱلۡيَوۡمَ لَا تُظۡلَمُ نَفۡسٞ شَيۡـٔٗا وَلَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Nítorí náà, ní òní wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. A kò sì níí san yín ní ẹ̀san àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّ أَصۡحَٰبَ ٱلۡجَنَّةِ ٱلۡيَوۡمَ فِي شُغُلٖ فَٰكِهُونَ
Dájúdájú ní òní, àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò kún fún ìgbádùn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
هُمۡ وَأَزۡوَٰجُهُمۡ فِي ظِلَٰلٍ عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ مُتَّكِـُٔونَ
Àwọn àti àwọn ìyàwó wọn yóò wà lábẹ́ àwọn ibòji, wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
لَهُمۡ فِيهَا فَٰكِهَةٞ وَلَهُم مَّا يَدَّعُونَ
Èso wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ohun tí wọ́n yóò máa bèèrè fún tún wà fún wọn pẹ̀lú.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
سَلَٰمٞ قَوۡلٗا مِّن رَّبّٖ رَّحِيمٖ
Àlàáfíà ni ọ̀rọ̀ tí ó má máa wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱمۡتَٰزُواْ ٱلۡيَوۡمَ أَيُّهَا ٱلۡمُجۡرِمُونَ
Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ bọ́ sí ọ̀tọ̀ ní òní.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
۞ أَلَمۡ أَعۡهَدۡ إِلَيۡكُمۡ يَٰبَنِيٓ ءَادَمَ أَن لَّا تَعۡبُدُواْ ٱلشَّيۡطَٰنَۖ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ
Ẹ̀yin ọmọ (Ànábì) Ādam, ṣe Èmi kò ti pa yín ní àṣẹ pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún aṣ-Ṣaetọ̄n? Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَأَنِ ٱعۡبُدُونِيۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ
Àti pé kí ẹ jọ́sìn fún Mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَقَدۡ أَضَلَّ مِنكُمۡ جِبِلّٗا كَثِيرًاۖ أَفَلَمۡ تَكُونُواْ تَعۡقِلُونَ
Àti pé (aṣ-Ṣaetọ̄n) kúkú ti ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀dá lọ́nà nínú yín. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
هَٰذِهِۦ جَهَنَّمُ ٱلَّتِي كُنتُمۡ تُوعَدُونَ
Èyí ni iná Jahanamọ tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ٱصۡلَوۡهَا ٱلۡيَوۡمَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ
Ẹ wọ inú rẹ̀ ní òní nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ٱلۡيَوۡمَ نَخۡتِمُ عَلَىٰٓ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَتُكَلِّمُنَآ أَيۡدِيهِمۡ وَتَشۡهَدُ أَرۡجُلُهُم بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Ní òní, A máa di ẹnu wọn pa. Àwọn ọwọ́ wọn yó sì máa bá Wa sọ̀rọ̀. Àwọn ẹsẹ̀ wọn yó sì máa jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَوۡ نَشَآءُ لَطَمَسۡنَا عَلَىٰٓ أَعۡيُنِهِمۡ فَٱسۡتَبَقُواْ ٱلصِّرَٰطَ فَأَنَّىٰ يُبۡصِرُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fọ́ wọn lójú, wọn ìbá sì yára wá si ojú ọ̀nà, báwo ni wọ́n ṣe máa ríran ná?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَوۡ نَشَآءُ لَمَسَخۡنَٰهُمۡ عَلَىٰ مَكَانَتِهِمۡ فَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ مُضِيّٗا وَلَا يَرۡجِعُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá yí wọn padà sí ẹ̀dá mìíràn nínú ibùgbé wọn. Wọn kò sì níí lágbára láti lọ síwájú. Wọn kò sì níí padà sẹ́yìn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَن نُّعَمِّرۡهُ نُنَكِّسۡهُ فِي ٱلۡخَلۡقِۚ أَفَلَا يَعۡقِلُونَ
Ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ẹ̀mí gígùn lò, A óò sọ ẹ̀dá rẹ̀ di ọ̀lẹ, ṣé wọn kò níí ṣe làákàyè ni!
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَا عَلَّمۡنَٰهُ ٱلشِّعۡرَ وَمَا يَنۢبَغِي لَهُۥٓۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ وَقُرۡءَانٞ مُّبِينٞ
A kò kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ewì. Kò yẹ ẹ́ (kò sì rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti kéwì). Kí ni ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí i) bí kò ṣe ìrántí àti al-Ƙur’ān pọ́nńbélé
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
لِّيُنذِرَ مَن كَانَ حَيّٗا وَيَحِقَّ ٱلۡقَوۡلُ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ alààyè àti nítorí kí ọ̀rọ̀ náà lè kò lórí àwọn aláìgbàgbọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا خَلَقۡنَا لَهُم مِّمَّا عَمِلَتۡ أَيۡدِينَآ أَنۡعَٰمٗا فَهُمۡ لَهَا مَٰلِكُونَ
Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá nínú ohun tí A fi ọwọ́ Wa ṣe (tí ó jẹ́) àwọn ẹran-ọ̀sìn fún wọn? Wọ́n sì ní ìkápá lórí wọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَذَلَّلۡنَٰهَا لَهُمۡ فَمِنۡهَا رَكُوبُهُمۡ وَمِنۡهَا يَأۡكُلُونَ
A tẹ̀ wọ́n lórí ba fún wọn; wọ́n ń gùn nínú wọn, wọ́n sì ń jẹ nínú wọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَهُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ وَمَشَارِبُۚ أَفَلَا يَشۡكُرُونَ
Àwọn àǹfààní àti ohun mímu tún wà fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ ءَالِهَةٗ لَّعَلَّهُمۡ يُنصَرُونَ
Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣàrànṣe fún wọn!
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
لَا يَسۡتَطِيعُونَ نَصۡرَهُمۡ وَهُمۡ لَهُمۡ جُندٞ مُّحۡضَرُونَ
Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún wọn; ṣebí àwọn òrìṣà ni ọmọ ogun tí (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná fún àwọn abọ̀rìṣà (láti fi jẹ wọ́n níyà).[1]
[1] Ẹ wo sūrah Mọryam; 19:82 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:98.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَا يَحۡزُنكَ قَوۡلُهُمۡۘ إِنَّا نَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَ
Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú Àwa mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَوَلَمۡ يَرَ ٱلۡإِنسَٰنُ أَنَّا خَلَقۡنَٰهُ مِن نُّطۡفَةٖ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٞ مُّبِينٞ
Ṣé ènìyàn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú àtọ̀? (Ṣebí lẹ́yìn) ìgbà náà l’ó di alátakò pọ́nńbélé.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَضَرَبَ لَنَا مَثَلٗا وَنَسِيَ خَلۡقَهُۥۖ قَالَ مَن يُحۡيِ ٱلۡعِظَٰمَ وَهِيَ رَمِيمٞ
Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa.[1] Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: “Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun?”
[1] Ìyẹn ni pé, ènìyàn ń fi agbára ẹ̀dá tí kò lè jí òkú dìde wé agbára Allāhu tí ó lè jí òkú dìde.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قُلۡ يُحۡيِيهَا ٱلَّذِيٓ أَنشَأَهَآ أَوَّلَ مَرَّةٖۖ وَهُوَ بِكُلِّ خَلۡقٍ عَلِيمٌ
Sọ pé: “Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلشَّجَرِ ٱلۡأَخۡضَرِ نَارٗا فَإِذَآ أَنتُم مِّنۡهُ تُوقِدُونَ
(Òun ni) Ẹni tí Ó mú iná jáde fún yín láti ara igi tútù. Ẹ sì ń fi dáná.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَوَلَيۡسَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يَخۡلُقَ مِثۡلَهُمۚ بَلَىٰ وَهُوَ ٱلۡخَلَّٰقُ ٱلۡعَلِيمُ
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò ní agbára láti dá irú wọn (mìíràn) bí? Bẹ́ẹ̀ ni (Ó ní agbára). Òun sì ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّمَآ أَمۡرُهُۥٓ إِذَآ أَرَادَ شَيۡـًٔا أَن يَقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَسُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي بِيَدِهِۦ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيۡءٖ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Nítorí náà, mímọ́ ni fún Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
 
مەنالار تەرجىمىسى سۈرە: ياسىن
سۈرە مۇندەرىجىسى بەت نومۇرى
 
قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى- ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

شەيىخ ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل ئەيكۇينى تەرجىمە قىلغان.

تاقاش