Check out the new design

د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل * - د ژباړو فهرست (لړلیک)

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

د معناګانو ژباړه سورت: بلد   آیت:

Al-Balad

لَآ أُقۡسِمُ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ
Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìí[1] búra.
[1] Allāhu lè fi ohunkóhun búra, àmọ́ fífi Allāhu nìkan ṣoṣo búra ni ẹ̀sìn gbà àwa láyè mọ láti fi búra. Bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ (ẹbọ ṣíṣe) sì ni fífi n̄ǹkan mìíràn búra lẹ́yìn Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.
عربي تفسیرونه:
وَأَنتَ حِلُّۢ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ
Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).[1]
[1] Ẹ̀tọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni kíkógun ja ìlú Mọkkah lásìkò ogun Ìṣí Mọkkah “Fat-hu Mọkkah”. Ṣíwájú àsìkò yìí àti lẹ́yìn rẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti jagun nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé.
عربي تفسیرونه:
وَوَالِدٖ وَمَا وَلَدَ
Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.
عربي تفسیرونه:
لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِي كَبَدٍ
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.
عربي تفسیرونه:
أَيَحۡسَبُ أَن لَّن يَقۡدِرَ عَلَيۡهِ أَحَدٞ
Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?
عربي تفسیرونه:
يَقُولُ أَهۡلَكۡتُ مَالٗا لُّبَدًا
Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”
عربي تفسیرونه:
أَيَحۡسَبُ أَن لَّمۡ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ
Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?
عربي تفسیرونه:
أَلَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ عَيۡنَيۡنِ
Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?
عربي تفسیرونه:
وَلِسَانٗا وَشَفَتَيۡنِ
Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?
عربي تفسیرونه:
وَهَدَيۡنَٰهُ ٱلنَّجۡدَيۡنِ
A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.
عربي تفسیرونه:
فَلَا ٱقۡتَحَمَ ٱلۡعَقَبَةَ
Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!
عربي تفسیرونه:
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡعَقَبَةُ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?
عربي تفسیرونه:
فَكُّ رَقَبَةٍ
(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.
عربي تفسیرونه:
أَوۡ إِطۡعَٰمٞ فِي يَوۡمٖ ذِي مَسۡغَبَةٖ
Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.
عربي تفسیرونه:
يَتِيمٗا ذَا مَقۡرَبَةٍ
(Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,
عربي تفسیرونه:
أَوۡ مِسۡكِينٗا ذَا مَتۡرَبَةٖ
tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).
عربي تفسیرونه:
ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡمَرۡحَمَةِ
Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.
عربي تفسیرونه:
أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ
Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.
عربي تفسیرونه:
 
د معناګانو ژباړه سورت: بلد
د سورتونو فهرست (لړلیک) د مخ نمبر
 
د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل - د ژباړو فهرست (لړلیک)

ژباړوونکی: شیخ أبو رحیمة میکائیل ایکوییني.

بندول