Check out the new design

د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل * - د ژباړو فهرست (لړلیک)

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

د معناګانو ژباړه سورت: تحریم   آیت:

At-Tah'riim

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ لِمَ تُحَرِّمُ مَآ أَحَلَّ ٱللَّهُ لَكَۖ تَبۡتَغِي مَرۡضَاتَ أَزۡوَٰجِكَۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Ìwọ Ànábì, nítorí kí ni o ṣe máa sọ n̄ǹkan tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ di èèwọ̀? Ìwọ ń wá ìyọ́nú àwọn ìyàwó rẹ. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
عربي تفسیرونه:
قَدۡ فَرَضَ ٱللَّهُ لَكُمۡ تَحِلَّةَ أَيۡمَٰنِكُمۡۚ وَٱللَّهُ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ
Dájúdájú Allāhu ti ṣe àlàyé òfin ìtánràn ìbúra yín fún yín. Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ yín. Òun sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.[1]
[1] Òfin ìtánràn ìbúra wà nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:89.
عربي تفسیرونه:
وَإِذۡ أَسَرَّ ٱلنَّبِيُّ إِلَىٰ بَعۡضِ أَزۡوَٰجِهِۦ حَدِيثٗا فَلَمَّا نَبَّأَتۡ بِهِۦ وَأَظۡهَرَهُ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ عَرَّفَ بَعۡضَهُۥ وَأَعۡرَضَ عَنۢ بَعۡضٖۖ فَلَمَّا نَبَّأَهَا بِهِۦ قَالَتۡ مَنۡ أَنۢبَأَكَ هَٰذَاۖ قَالَ نَبَّأَنِيَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡخَبِيرُ
Rántí nígbà tí Ànábì bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ s’ọ̀rọ̀ àṣírí. Nígbà tí (ẹni tó bá sọ̀rọ̀, ìyẹn Hafsọh) sì sọ̀rọ̀ náà fún (‘Ā’iṣah), Allāhu sì fi han Ànábì (pé ẹlòmíìràn ti gbọ́ sí i).[1] Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ apá kan rẹ̀ (fún Hafsọh pé: “O ti fi ọ̀rọ̀ Mọ̄riyah tó ‘Ā’iṣah létí.”). Ó sì fi apá kan sílẹ̀ (ìyẹn, ọ̀rọ̀ nípa ipò àrólé). Àmọ́ nígbà tí (Ànábì) fi ìró náà tó o létí, Hafsọh) sọ pé: “Ta ni ó fún ọ ní ìró èyí?” (Ànábì) sọ pé: “Onímọ̀, Alámọ̀tán l’Ó fún mi ní ìró náà.”
[1] Méjì ni ọ̀rọ̀ àṣírí náà. Ìkíní: bíbúra tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fi Allāhu búra pé òun kò níí fẹ́ ẹrúbìnrin rẹ̀ kan, Mọ̄riyah Ƙibtiyyah - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ẹni tó bí ’Ibrọ̄hīm fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ìkejì: sísọ tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé Abu Bakr Siddīƙ ni àrólé àkọ́kọ́, ‘Umọr ọmọ Kattọ̄b sì ni àrólé kejì - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - .
عربي تفسیرونه:
إِن تَتُوبَآ إِلَى ٱللَّهِ فَقَدۡ صَغَتۡ قُلُوبُكُمَاۖ وَإِن تَظَٰهَرَا عَلَيۡهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ مَوۡلَىٰهُ وَجِبۡرِيلُ وَصَٰلِحُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ بَعۡدَ ذَٰلِكَ ظَهِيرٌ
Tí ẹ̀yin méjèèjì bá ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu, (Ó máa gba ìronúpìwàdà yín). Ṣebí ọkàn yín kúkú ti tẹ̀ (síbi kí Ànábì má fẹ̀ẹ́ Mọ̄riyah). Tí ẹ bá sì ran ara yín lọ́wọ́ (láti kó ìbànújẹ́) bá a, dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, àti (mọlāika) Jibrīl àti ẹni rere nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn mọlāika tí wọ́n jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (tún wà fún un).
عربي تفسیرونه:
عَسَىٰ رَبُّهُۥٓ إِن طَلَّقَكُنَّ أَن يُبۡدِلَهُۥٓ أَزۡوَٰجًا خَيۡرٗا مِّنكُنَّ مُسۡلِمَٰتٖ مُّؤۡمِنَٰتٖ قَٰنِتَٰتٖ تَٰٓئِبَٰتٍ عَٰبِدَٰتٖ سَٰٓئِحَٰتٖ ثَيِّبَٰتٖ وَأَبۡكَارٗا
Ó ṣeé ṣe, tí ó bá kọ̀ yín sílẹ̀, kí Olúwa rẹ̀ fi àwọn obìnrin kan, tí wọn lóore jù yín lọ rọ́pò fún un, (tí wọ́n máa jẹ́) mùsùlùmí, onígbàgbọ́ òdodo, olùtẹ̀lé-àṣẹ, olùronúpìwàdà, olùjọ́sìn, olùgbààwẹ̀ (tí wọ́n máa jẹ́) adélébọ̀ àti wúńdíá.
عربي تفسیرونه:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ وَأَهۡلِيكُمۡ نَارٗا وَقُودُهَا ٱلنَّاسُ وَٱلۡحِجَارَةُ عَلَيۡهَا مَلَٰٓئِكَةٌ غِلَاظٞ شِدَادٞ لَّا يَعۡصُونَ ٱللَّهَ مَآ أَمَرَهُمۡ وَيَفۡعَلُونَ مَا يُؤۡمَرُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí ara yín àti àwọn ará ilé yín níbi Iná. Ènìyàn àti òkúta ni n̄ǹkan ìkoná rẹ̀. Àwọn mọlāika tó rorò, tí wọ́n le ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. Wọn kò níí yapa àṣẹ Allāhu níbi ohun tí Ó bá pa láṣẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá pa láṣẹ fún wọn.
عربي تفسیرونه:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَعۡتَذِرُواْ ٱلۡيَوۡمَۖ إِنَّمَا تُجۡزَوۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ ṣàì gbàgbọ́, ẹ má ṣe ṣàròyé ní ọjọ́ òní. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.
عربي تفسیرونه:
 
د معناګانو ژباړه سورت: تحریم
د سورتونو فهرست (لړلیک) د مخ نمبر
 
د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل - د ژباړو فهرست (لړلیک)

ژباړوونکی: شیخ أبو رحیمة میکائیل ایکوییني.

بندول