Check out the new design

د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل * - د ژباړو فهرست (لړلیک)

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

د معناګانو ژباړه سورت: تغابن   آیت:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَآ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.
عربي تفسیرونه:
مَآ أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ وَمَن يُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ يَهۡدِ قَلۡبَهُۥۚ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
Àdánwò kan kò lè ṣẹlẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu ní òdodo, Allāhu máa fi ọkàn rẹ̀ mọ̀nà.[1] Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
[1] Ìmọ̀nà ọkàn lórí àdánwò ni gbígba kádàrá, ṣíṣe sùúrù àti níní ìrètí sí ẹ̀san rere.
عربي تفسیرونه:
وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُواْ ٱلرَّسُولَۚ فَإِن تَوَلَّيۡتُمۡ فَإِنَّمَا عَلَىٰ رَسُولِنَا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá gbúnrí, ìkede ẹ̀sìn tó yanjú ni ojúṣe Òjíṣẹ́ Wa.
عربي تفسیرونه:
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
عربي تفسیرونه:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ مِنۡ أَزۡوَٰجِكُمۡ وَأَوۡلَٰدِكُمۡ عَدُوّٗا لَّكُمۡ فَٱحۡذَرُوهُمۡۚ وَإِن تَعۡفُواْ وَتَصۡفَحُواْ وَتَغۡفِرُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọ̀tá wà fún yín nínú àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún wọn. Tí ẹ bá ṣàmójúkúrò, tí ẹ ṣàfojúfò, tí ẹ sì ṣàforíjìn (fún wọn), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
عربي تفسیرونه:
إِنَّمَآ أَمۡوَٰلُكُمۡ وَأَوۡلَٰدُكُمۡ فِتۡنَةٞۚ وَٱللَّهُ عِندَهُۥٓ أَجۡرٌ عَظِيمٞ
Ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín. Allāhu sì ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
عربي تفسیرونه:
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُمۡ وَٱسۡمَعُواْ وَأَطِيعُواْ وَأَنفِقُواْ خَيۡرٗا لِّأَنفُسِكُمۡۗ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفۡسِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ (Allāhu), ẹ tẹ̀lé e, kí ẹ sì náwó (fún ẹ̀sìn Rẹ̀) lóore jùlọ fún ẹ̀mí yín. Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.
عربي تفسیرونه:
إِن تُقۡرِضُواْ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنٗا يُضَٰعِفۡهُ لَكُمۡ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡۚ وَٱللَّهُ شَكُورٌ حَلِيمٌ
Tí ẹ bá yá Allāhu ní dúkìá tó dára, Ó máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́pẹ́[1], Aláfaradà,
[1] Nínú orúkọ àti ìròyìn Allāhu ni “Ṣākir” àti “Ṣakūr”.
عربي تفسیرونه:
عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
عربي تفسیرونه:
 
د معناګانو ژباړه سورت: تغابن
د سورتونو فهرست (لړلیک) د مخ نمبر
 
د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل - د ژباړو فهرست (لړلیک)

ژباړوونکی: شیخ أبو رحیمة میکائیل ایکوییني.

بندول