Check out the new design

د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل * - د ژباړو فهرست (لړلیک)

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

د معناګانو ژباړه آیت: (3) سورت: نساء
وَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تُقۡسِطُواْ فِي ٱلۡيَتَٰمَىٰ فَٱنكِحُواْ مَا طَابَ لَكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ مَثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تَعۡدِلُواْ فَوَٰحِدَةً أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَلَّا تَعُولُواْ
Tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé nípa (fífẹ́) ọmọ òrukàn,[1] ẹ fẹ́ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ si yín nínú àwọn obìnrin; méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin.[2] Ṣùgbọ́n tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé, (ẹ fẹ́) ẹyọ kan tàbí ẹrúbìnrin yín. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ pé ẹ ò níí ṣàbòsí.
[1] Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ẹni tí ó ń mójútó ọmọ òrukàn obìnrin nífẹ̀ẹ́ láti fẹ́ ọmọbìnrin náà lẹ́yìn tí ó bàlágà tán, àmọ́ ọkùnrin náà kọ̀ láti fún un ní sọ̀daàkí rẹ̀ nítorí pé, ó mọ bí ogún ọmọbìnrin náà ṣe tó ní iye. [2]Láti ọ̀dọ̀ ọmọ Ṣihāb, dájúdájú ó gbọ́ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ fún ọkùnrin kan láti ìdìlé Thaƙīf tí ó gba ’Islām, tí ìyàwó rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́wàá ní àsìkò tí ó gba ’Islām pé, “Mú mẹ́rin nínú wọn, kí o sì kọ àwọn yòókù sílẹ̀.” (Muwattọ’u Imām Mọ̄lik, Musnad Ṣāfi‘iy, Sunan Baehaƙiy àti Sọhīhu bn Hibbān)
عربي تفسیرونه:
 
د معناګانو ژباړه آیت: (3) سورت: نساء
د سورتونو فهرست (لړلیک) د مخ نمبر
 
د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل - د ژباړو فهرست (لړلیک)

ژباړوونکی: شیخ أبو رحیمة میکائیل ایکوییني.

بندول