Check out the new design

د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل * - د ژباړو فهرست (لړلیک)

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

د معناګانو ژباړه سورت: صافات   آیت:
فَلَمَّآ أَسۡلَمَا وَتَلَّهُۥ لِلۡجَبِينِ
Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú[1] (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀,
[1] Ìtúmọ̀ “jẹbīn” ni iwájú orí.
عربي تفسیرونه:
وَنَٰدَيۡنَٰهُ أَن يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ
A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm,
عربي تفسیرونه:
قَدۡ صَدَّقۡتَ ٱلرُّءۡيَآۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
عربي تفسیرونه:
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡبَلَٰٓؤُاْ ٱلۡمُبِينُ
Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé.
عربي تفسیرونه:
وَفَدَيۡنَٰهُ بِذِبۡحٍ عَظِيمٖ
A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀.
عربي تفسیرونه:
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
عربي تفسیرونه:
سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
عربي تفسیرونه:
كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
عربي تفسیرونه:
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
عربي تفسیرونه:
وَبَشَّرۡنَٰهُ بِإِسۡحَٰقَ نَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere.
عربي تفسیرونه:
وَبَٰرَكۡنَا عَلَيۡهِ وَعَلَىٰٓ إِسۡحَٰقَۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحۡسِنٞ وَظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ مُبِينٞ
Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (tó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.[1]
[1] Bẹ̀rẹ̀ láti āyah 100 títí dé āyah 113, ó ti hàn kedere pé: (ìkíní) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni àkọ́bí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a -; (ìkejì) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni ẹni tí Allāhu Ẹlẹ́dàá pa láṣẹ pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - pa láti fi jọ́sìn fún Òun; (ìkẹta) Kò sí ohun tó jẹmọ́ ẹ̀jẹ́ àti ìmúṣẹ ẹ̀jẹ́ nínú àlá àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà; (ìkẹrin) Ìkíní kejì àwọn ọmọ méjèèjì náà ni ẹni ìbùkún.
عربي تفسیرونه:
وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ
Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
عربي تفسیرونه:
وَنَجَّيۡنَٰهُمَا وَقَوۡمَهُمَا مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ
A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
عربي تفسیرونه:
وَنَصَرۡنَٰهُمۡ فَكَانُواْ هُمُ ٱلۡغَٰلِبِينَ
A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn).
عربي تفسیرونه:
وَءَاتَيۡنَٰهُمَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلۡمُسۡتَبِينَ
A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà tó yanjú.
عربي تفسیرونه:
وَهَدَيۡنَٰهُمَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ
A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà.
عربي تفسیرونه:
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِمَا فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
عربي تفسیرونه:
سَلَٰمٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
عربي تفسیرونه:
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
عربي تفسیرونه:
إِنَّهُمَا مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
عربي تفسیرونه:
وَإِنَّ إِلۡيَاسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
عربي تفسیرونه:
إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ أَلَا تَتَّقُونَ
(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni?
عربي تفسیرونه:
أَتَدۡعُونَ بَعۡلٗا وَتَذَرُونَ أَحۡسَنَ ٱلۡخَٰلِقِينَ
Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀?[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:14.
عربي تفسیرونه:
ٱللَّهَ رَبَّكُمۡ وَرَبَّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ
(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
عربي تفسیرونه:
 
د معناګانو ژباړه سورت: صافات
د سورتونو فهرست (لړلیک) د مخ نمبر
 
د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل - د ژباړو فهرست (لړلیک)

ژباړوونکی: شیخ أبو رحیمة میکائیل ایکوییني.

بندول