Check out the new design

ߞߎ߬ߙߣߊ߬ ߞߟߊߒߞߋ ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߦߙߏߓߊߞߊ߲ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߊ߬ߓߎ߰-ߙߊ߬ߤ߭ߌ߯ߡߊ߫ ߡߌߞߊߌߟߎ߫ * - ߘߟߊߡߌߘߊ ߟߎ߫ ߦߌ߬ߘߊ߬ߥߟߊ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌ߬ߘߊ߬ߟߌ ߝߐߘߊ ߘߏ߫: ߞߐ߲߬ߞߍ   ߟߝߊߙߌ ߘߏ߫:
أَمۡ تَأۡمُرُهُمۡ أَحۡلَٰمُهُم بِهَٰذَآۚ أَمۡ هُمۡ قَوۡمٞ طَاغُونَ
Tàbí ọpọlọ wọn ló ń pa wọ́n láṣẹ èyí ni? Tàbí ìjọ alákọyọ ni wọ́n ni?
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ يَقُولُونَ تَقَوَّلَهُۥۚ بَل لَّا يُؤۡمِنُونَ
Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni.” Rárá o, wọn kò gbàgbọ́ ni.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
فَلۡيَأۡتُواْ بِحَدِيثٖ مِّثۡلِهِۦٓ إِن كَانُواْ صَٰدِقِينَ
Kí àwọn náà mú ọ̀rọ̀ kan bí irú rẹ̀ wá tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ خُلِقُواْ مِنۡ غَيۡرِ شَيۡءٍ أَمۡ هُمُ ٱلۡخَٰلِقُونَ
Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ خَلَقُواْ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۚ بَل لَّا يُوقِنُونَ
Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ عِندَهُمۡ خَزَآئِنُ رَبِّكَ أَمۡ هُمُ ٱلۡمُصَۜيۡطِرُونَ
Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn ilé ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí?
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ لَهُمۡ سُلَّمٞ يَسۡتَمِعُونَ فِيهِۖ فَلۡيَأۡتِ مُسۡتَمِعُهُم بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٍ
Tàbí wọ́n ní àkàbà kan tí wọ́n ń fi gbọ́rọ̀ (nínú sánmọ̀)? Kí ẹni tí ó ń bá wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ mú ẹ̀rí tó yanjú wá?
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ لَهُ ٱلۡبَنَٰتُ وَلَكُمُ ٱلۡبَنُونَ
Tàbí àwọn ọmọbìnrin ni tiRẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì ni tiyín?
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ تَسۡـَٔلُهُمۡ أَجۡرٗا فَهُم مِّن مَّغۡرَمٖ مُّثۡقَلُونَ
Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ عِندَهُمُ ٱلۡغَيۡبُ فَهُمۡ يَكۡتُبُونَ
Tàbí ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sílẹ̀?
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ يُرِيدُونَ كَيۡدٗاۖ فَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ هُمُ ٱلۡمَكِيدُونَ
Tàbí wọ́n ń gbèrò ète kan ni? Nígbà náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn l’ó máa f’orí kó ète náà.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَمۡ لَهُمۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Tàbí wọ́n ní ọlọ́hun kan lẹ́yìn Allāhu ni? Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
وَإِن يَرَوۡاْ كِسۡفٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ سَاقِطٗا يَقُولُواْ سَحَابٞ مَّرۡكُومٞ
Tí wọ́n bá rí apá kan nínú sánmọ̀ tó ya lúlẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ ni (wọn kò níí gbàgbọ́).”
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
فَذَرۡهُمۡ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي فِيهِ يُصۡعَقُونَ
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ títí wọn yóò fi bá ọjọ́ wọn tí wọn máa pa wọ́n sínú rẹ̀ pàdé.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
يَوۡمَ لَا يُغۡنِي عَنۡهُمۡ كَيۡدُهُمۡ شَيۡـٔٗا وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ
Ọjọ́ tí ète wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
وَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ عَذَابٗا دُونَ ذَٰلِكَ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Àti pé dájúdájú ìyà kan ń bẹ fún àwọn tó ṣàbòsí yàtọ̀ sí (ìyà ọ̀run) yẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
وَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ فَإِنَّكَ بِأَعۡيُنِنَاۖ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ حِينَ تَقُومُ
Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ nígbà tí o bá fẹ́ dìde.[1]
[1] Nínú Sunan Abī Dāwud, láti ọ̀dọ̀ bàbá Barzah ’Azlamiy - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa ń sọ ní ìparí nígbà tí ó bá fẹ́ dìde kúrò lórí ìjókòó, « سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ وَبِحَمْدِكَ أَشْهَدُ أَنْ لاَ إِلَهَ إِلاَّ أَنْتَ أَسْتَغْفِرُكَ وَأَتُوبُ إِلَيْكَ ». “Subhānaka-llahummọ wabihamdika ’aṣhadu ’anlā ’ilāha ’illā ’anta ’astagfiruka wa ’atūbu ’ilaek” (Mímọ́ ni fún Allāhu, ẹyìn sì ni fún Ọ. Mò ń jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ìwọ. Mò ń tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ, mo sì ń ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ.) Ọkùnrin kan sọ pé, “Òjíṣẹ́ Allāhu, dájúdájú o sọ ọ̀rọ̀ kan tí o kì í sọ tẹ́tẹ̀tẹ́lẹ̀?” Ó sọ pé, “Pípa-ẹ̀ṣẹ̀-rẹ́ ni fún n̄ǹkan tí ó bá ṣẹlẹ̀ ní ìjókòó.” Albāniy sọ pé, “Ó dára, ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.”
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
وَمِنَ ٱلَّيۡلِ فَسَبِّحۡهُ وَإِدۡبَٰرَ ٱلنُّجُومِ
Àti pé ní alẹ́ àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán[1], ṣàfọ̀mọ́ fún Un.
[1] “nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán” àsìkò yẹn ni àsìkò tí fajr òdodo máa là.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
 
ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌ߬ߘߊ߬ߟߌ ߝߐߘߊ ߘߏ߫: ߞߐ߲߬ߞߍ
ߝߐߘߊ ߟߎ߫ ߦߌ߬ߘߊ߬ߥߟߊ ߞߐߜߍ ߝߙߍߕߍ
 
ߞߎ߬ߙߣߊ߬ ߞߟߊߒߞߋ ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߦߙߏߓߊߞߊ߲ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߊ߬ߓߎ߰-ߙߊ߬ߤ߭ߌ߯ߡߊ߫ ߡߌߞߊߌߟߎ߫ - ߘߟߊߡߌߘߊ ߟߎ߫ ߦߌ߬ߘߊ߬ߥߟߊ

ߗߍ߬ߡߐ߯ ߊ߬ߓߎ߰-ߙߊ߬ߤ߭ߌ߯ߡߊ߫ ߡߌߞߊߌߟߎ߫ ߊߦߑߞߏߓߌ߯ߣߌ߯ ߟߊ߫

ߘߊߕߎ߲߯ߠߌ߲