Check out the new design

ការបកប្រែអត្ថន័យនៃគម្ពីរគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល * - មាតិកានៃការបកប្រែ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ការបកប្រែអត្ថន័យ ជំពូក​: ហ្វូសស៊ីឡាត់   វាក្យខណ្ឌ:

Fussilat

حمٓ
Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
تَنزِيلٞ مِّنَ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Ìmísí kan (nìyí) tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
كِتَٰبٞ فُصِّلَتۡ ءَايَٰتُهُۥ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا لِّقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ
Tírà kan ni tí wọ́n ṣàlàyé àwọn āyah inú rẹ̀,[1] (ó ń jẹ́) al-Ƙur’ān (tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ní) èdè Lárúbáwá fún ìjọ tó nímọ̀.
[1] Ìtúmọ̀ mìíràn “Tírà kan ni tí wọ́n pín àwọn āyah inú rẹ̀ sínú àwọn sūrah.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
بَشِيرٗا وَنَذِيرٗا فَأَعۡرَضَ أَكۡثَرُهُمۡ فَهُمۡ لَا يَسۡمَعُونَ
(Ó jẹ́) ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gbúnrí kúrò níbẹ̀. Wọn kò sì tẹ́tí sí i.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَقَالُواْ قُلُوبُنَا فِيٓ أَكِنَّةٖ مِّمَّا تَدۡعُونَآ إِلَيۡهِ وَفِيٓ ءَاذَانِنَا وَقۡرٞ وَمِنۢ بَيۡنِنَا وَبَيۡنِكَ حِجَابٞ فَٱعۡمَلۡ إِنَّنَا عَٰمِلُونَ
Wọ́n sì wí pé: “Ọkàn wa wà ní títì pa sí ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí. Èdídí sì wà nínú etí wa. Àti pé gàgá wà láààrin àwa àti ìwọ. Nítorí náà, máa ṣe tìrẹ. Dájúdájú àwa náà ń ṣe tiwa.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يُوحَىٰٓ إِلَيَّ أَنَّمَآ إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَٱسۡتَقِيمُوٓاْ إِلَيۡهِ وَٱسۡتَغۡفِرُوهُۗ وَوَيۡلٞ لِّلۡمُشۡرِكِينَ
Sọ pé: “Abara bí irú yín kúkú ni èmi náà. Wọ́n ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi ni, pé Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin tì Í (nínú ìjọ́sìn), kí ẹ sì tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ègbé sì ni fún àwọn ọ̀ṣẹbọ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ
Àwọn tí kò yọ Zakāh, àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.[1]
[1] Bí āyah yìí bá sọpọ̀ mọ́ āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀, “zakāh” máa dúró fún àfọ̀mọ́ ọkàn àti àfọ̀mọ́ ara. Àmọ́ tí āyah yìí bá dádúró, “zakāh” máa túmọ̀ sí àfọ̀mọ́ dúkìá.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونٖ
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pẹ̀dín tí kò níí dáwọ́ dúró ń bẹ fún wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
۞ قُلۡ أَئِنَّكُمۡ لَتَكۡفُرُونَ بِٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَرۡضَ فِي يَوۡمَيۡنِ وَتَجۡعَلُونَ لَهُۥٓ أَندَادٗاۚ ذَٰلِكَ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Sọ pé: “Ṣé dájúdájú ẹ̀yin máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ fún ọjọ́ méjì, ẹ sì ń sọ (ẹ̀dá Rẹ̀) di akẹgbẹ́ Rẹ̀ (tí ẹ̀ ń bọ wọ́n)?” Ìyẹn (Ẹlẹ́dàá ilẹ̀) sì ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَجَعَلَ فِيهَا رَوَٰسِيَ مِن فَوۡقِهَا وَبَٰرَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَآ أَقۡوَٰتَهَا فِيٓ أَرۡبَعَةِ أَيَّامٖ سَوَآءٗ لِّلسَّآئِلِينَ
Ó sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin.[1] (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀).
[1] Bí Allāhu ṣe gbàròyìn pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”, bẹ́ẹ̀ náà l’Ó ṣe gbàròyìn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, èyí tí í ṣe ìdà kejì ìkánjú. Nítorí náà, Allāhu lágbára láti ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run láààrin ohun tí ó kéré jùlọ sí ìṣẹ́jú kan. Bí Allāhu bá sì lo òǹkà ọjọ́ kan fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àṣẹ “Jẹ́-bẹ́ẹ̀” kò jẹ́ tiRẹ̀. Ọba Aṣèyí-ó-wù-Ú ni.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰٓ إِلَى ٱلسَّمَآءِ وَهِيَ دُخَانٞ فَقَالَ لَهَا وَلِلۡأَرۡضِ ٱئۡتِيَا طَوۡعًا أَوۡ كَرۡهٗا قَالَتَآ أَتَيۡنَا طَآئِعِينَ
Lẹ́yìn náà, Allāhu wà ní òkè sánmọ̀, nígbà tí sánmọ̀ wà ní èéfín. Ó sì sọ fún òhun àti ilẹ̀ pé: “Ẹ wá bí ẹ fẹ́ tàbí ẹ kọ̀.” Àwọn méjèèjì sọ pé: “A wá pẹ̀lú ìfínnú-fíndọ̀.”[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Anbiyā’; 21:30.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَقَضَىٰهُنَّ سَبۡعَ سَمَٰوَاتٖ فِي يَوۡمَيۡنِ وَأَوۡحَىٰ فِي كُلِّ سَمَآءٍ أَمۡرَهَاۚ وَزَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِمَصَٰبِيحَ وَحِفۡظٗاۚ ذَٰلِكَ تَقۡدِيرُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ
Ó sì parí (ìṣẹ̀dá) rẹ̀ sí sánmọ̀ méje fún ọjọ́ méjì. Ó sì fi iṣẹ́ sánmọ̀ kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sínú rẹ̀. A sì fi àwọn àtùpà (ìràwọ̀) ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ àti ààbò (fún un). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَإِنۡ أَعۡرَضُواْ فَقُلۡ أَنذَرۡتُكُمۡ صَٰعِقَةٗ مِّثۡلَ صَٰعِقَةِ عَادٖ وَثَمُودَ
Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ pé: “Èmi ń ṣèkìlọ̀ iná láti ojú sánmọ̀ irú iná láti ojú sánmọ̀ tó gbá ìjọ ‘Ād àti Thamūd mú fún yín ni.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِذۡ جَآءَتۡهُمُ ٱلرُّسُلُ مِنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۖ قَالُواْ لَوۡ شَآءَ رَبُّنَا لَأَنزَلَ مَلَٰٓئِكَةٗ فَإِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn níwájú wọn àti lẹ́yìn wọn,[1] (wọ́n sọ) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Allāhu.” Wọ́n wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa wa bá fẹ́ ni, ìbá sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ (fún ìpèpè yìí). Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́.”
[1] “níwájú wọn” túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - wá bá àwọn bàbá ńlá wọn, “lẹ́yìn wọn” sì túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu tún wá bá àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn lẹ́yìn ìparun àwọn bàbá ńlá wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَأَمَّا عَادٞ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَقَالُواْ مَنۡ أَشَدُّ مِنَّا قُوَّةًۖ أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ ٱلَّذِي خَلَقَهُمۡ هُوَ أَشَدُّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗۖ وَكَانُواْ بِـَٔايَٰتِنَا يَجۡحَدُونَ
Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì wí pé: “Ta ni ó lágbára jù wá lọ ná?” Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu tí Ó ṣẹ̀dá wọn, Ó ní agbára jù wọ́n lọ ni? Wọ́n sì ń tako àwọn āyah Wa!
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا صَرۡصَرٗا فِيٓ أَيَّامٖ نَّحِسَاتٖ لِّنُذِيقَهُمۡ عَذَابَ ٱلۡخِزۡيِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَخۡزَىٰۖ وَهُمۡ لَا يُنصَرُونَ
Nítorí náà, A rán atẹ́gùn líle sí wọn ní àwọn ọjọ́ burúkú kan nítorí kí Á lè jẹ́ kí wọ́n tọ́ ìyà yẹpẹrẹ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì máa yẹpẹrẹ wọn jùlọ; Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.[1]
[1] Àwọn “nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:19, Allāhu dárúkọ ọjọ́ kan fún ìparun ìjọ ‘Ād. Àmọ́ nínú sūrah al-Hāƙƙọh; 69:7, Allāhu dárúkọ òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ fún ìparun wọn. Nínú sūrah Fussilat; 41:16, Allāhu dárúkọ àwọn ọjọ́? Wọ́n ní, “Nítorí náà, ìtakora ti jẹyọ lórí òǹkà ọjọ́ ti Allāhu fi pa ìjọ ‘Ād run! Èsì: Kò sí ìtakora láààrin àwọn āyah náà. Àlàyé rẹ̀ nìyí, āyah ti sūrah al-Ƙọmọr tó pè é ní ọjọ́ kan sọ pé “ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.” Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, “ọjọ́ kan” di “àwọn ọjọ́ kan” nínú āyah ti sūrah Fussilat. Àmọ́ àpapọ̀ òǹkà ọjọ́ ìparun wọn l’ó jẹyọ nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh. Ṣé ẹ ti rí i báyìí pé, àìnímọ̀ nípa èto láààrin àwọn āyah lè ṣokùnfà ìtakora āyah lójú àwọn aláìmọ̀kan.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَأَمَّا ثَمُودُ فَهَدَيۡنَٰهُمۡ فَٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡعَمَىٰ عَلَى ٱلۡهُدَىٰ فَأَخَذَتۡهُمۡ صَٰعِقَةُ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡهُونِ بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Ní ti ìjọ Thamūd, A ṣàlàyé ìmọ̀nà fún wọn,[1] ṣùgbọ́n wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àìríran dípò ìmọ̀nà. Nítorí náà, ìyà iná láti ojú sánmọ̀ tó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá gbá wọn mú nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
[1] Ìyẹn nípasẹ̀ pé Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - rán àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَنَجَّيۡنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ
A sì gba àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu) là.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَيَوۡمَ يُحۡشَرُ أَعۡدَآءُ ٱللَّهِ إِلَى ٱلنَّارِ فَهُمۡ يُوزَعُونَ
Ní ọjọ́ tí wọ́n máa kó àwọn ọ̀tá Allāhu jọ síbi Iná, wọn yó sì kó àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn papọ̀ mọ́ àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
حَتَّىٰٓ إِذَا مَا جَآءُوهَا شَهِدَ عَلَيۡهِمۡ سَمۡعُهُمۡ وَأَبۡصَٰرُهُمۡ وَجُلُودُهُم بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀ tán, ìgbọ́rọ̀ wọn, ìríran wọn àti awọ ara wọn yó sì máa jẹ́rìí lé wọn lórí nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَقَالُواْ لِجُلُودِهِمۡ لِمَ شَهِدتُّمۡ عَلَيۡنَاۖ قَالُوٓاْ أَنطَقَنَا ٱللَّهُ ٱلَّذِيٓ أَنطَقَ كُلَّ شَيۡءٖۚ وَهُوَ خَلَقَكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٖ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Wọn yóò wí fún awọ ara wọn pé: “Nítorí kí ni ẹ ṣe jẹ́rìí lé wa lórí ná?” Wọ́n yóò sọ pé: “Allāhu, Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ọ̀rọ̀ sọ, Òun l’Ó fún wa ní ọ̀rọ̀ sọ. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمَا كُنتُمۡ تَسۡتَتِرُونَ أَن يَشۡهَدَ عَلَيۡكُمۡ سَمۡعُكُمۡ وَلَآ أَبۡصَٰرُكُمۡ وَلَا جُلُودُكُمۡ وَلَٰكِن ظَنَنتُمۡ أَنَّ ٱللَّهَ لَا يَعۡلَمُ كَثِيرٗا مِّمَّا تَعۡمَلُونَ
Ẹ̀yin kò lè para yín mọ́ (kúrò níbi ẹ̀ṣẹ̀, nítorí) kí ìgbọ́rọ̀ yín, ìríran yín àti awọ ara yín má fi lè jẹ́rìí le yín lórí. Ṣùgbọ́n ẹ lérò pé dájúdájú Allāhu kò mọ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَذَٰلِكُمۡ ظَنُّكُمُ ٱلَّذِي ظَنَنتُم بِرَبِّكُمۡ أَرۡدَىٰكُمۡ فَأَصۡبَحۡتُم مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ
Ìyẹn, èrò ọkàn yín tí ẹ lérò sí Olúwa yín ló kó ìparun ba yín. Ẹ sì di ẹni òfò.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَإِن يَصۡبِرُواْ فَٱلنَّارُ مَثۡوٗى لَّهُمۡۖ وَإِن يَسۡتَعۡتِبُواْ فَمَا هُم مِّنَ ٱلۡمُعۡتَبِينَ
Tí wọ́n bá ṣe sùúrù (fún ìyà), Iná kúkú ni ibùgbé fún wọn. Tí wọ́n bá sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti fi wá ìyọ́nú Allāhu (ní àsìkò yìí), wọn kò sí níí wà nínú àwọn tí wọ́n máa rí ìyọ́nú Allāhu gbà.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
۞ وَقَيَّضۡنَا لَهُمۡ قُرَنَآءَ فَزَيَّنُواْ لَهُم مَّا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَحَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ فِيٓ أُمَمٖ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ خَٰسِرِينَ
Àwa ti yan àwọn alábàárìn kan fún wọn,[1] tí wọ́n ṣe ohun tí ń bẹ níwájú wọn[2] àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn[3] ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀) sí àwọn ìjọ tó ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànǹú àti ènìyàn pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
[1] Ìyẹn ni pé, A ti yan àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n ẹlẹ́tàn kan fún wọn tí ó tàn wọ́n jẹ títí di ọjọ́ ikú wọn. [2] “ohun tí ń bẹ níwájú wọn” tí àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n wọn ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún wọn ni yòdòyìndìn, adùn àti ọ̀ṣọ́ ilé ayé tí ó mú wọn gbàgbé Allāhu. [3] “ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn” tí àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n wọn ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún wọn ni pé, kò níí sí àjíǹde, ìṣírò-iṣẹ́ àti ẹ̀san ní Ọjọ́ Àjíǹde. Wọ́n sì ń wí pé, “Lẹ́yìn ikú, sàréè ni!” Wọn kò sì mọ̀ pé, àjíǹde, ìṣírò-iṣẹ́ àti ẹ̀san ń bẹ lẹ́yìn sàréè. Ìdí nìyí tí wọn fi gbàgbé Allāhu pátápátá.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَسۡمَعُواْ لِهَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ وَٱلۡغَوۡاْ فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَغۡلِبُونَ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí al-Ƙur’ān yìí. Kí ẹ sì sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀ kí ẹ lè borí.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَلَنُذِيقَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَذَابٗا شَدِيدٗا وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَسۡوَأَ ٱلَّذِي كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Nítorí náà, dájúdájú A óò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìyà líle tọ́ wò. Àti pé dájúdájú A óò fi èyí tó burú ju èyí tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ذَٰلِكَ جَزَآءُ أَعۡدَآءِ ٱللَّهِ ٱلنَّارُۖ لَهُمۡ فِيهَا دَارُ ٱلۡخُلۡدِ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ بِـَٔايَٰتِنَا يَجۡحَدُونَ
Iná, ìyẹn ni ẹ̀san àwọn ọ̀tá Allāhu. Ilé gbére wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ó jẹ́ ẹ̀san nítorí pé wọ́n ń tako àwọn āyah Wa.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ رَبَّنَآ أَرِنَا ٱلَّذَيۡنِ أَضَلَّانَا مِنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِ نَجۡعَلۡهُمَا تَحۡتَ أَقۡدَامِنَا لِيَكُونَا مِنَ ٱلۡأَسۡفَلِينَ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Olúwa wa, fi àwọn méjèèjì tí wọ́n ṣì wá lọ́nà nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn hàn wá, kí á fi àwọn méjèèjì sí abẹ́ ẹsẹ̀ wa, nítorí kí àwọn méjèèjì lè wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّ ٱلَّذِينَ قَالُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُ ثُمَّ ٱسۡتَقَٰمُواْ تَتَنَزَّلُ عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ أَلَّا تَخَافُواْ وَلَا تَحۡزَنُواْ وَأَبۡشِرُواْ بِٱلۡجَنَّةِ ٱلَّتِي كُنتُمۡ تُوعَدُونَ
Dájúdájú àwọn tó sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin (sínú ẹ̀sìn títí di ọjọ́ ikú wọn), àwọn mọlāika yóò máa sọ̀kalẹ̀ wá bá wọn (ní ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì máa sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà, ẹ má ṣe banújẹ́. Kí ẹ sì dunnú sí Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
نَحۡنُ أَوۡلِيَآؤُكُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِۖ وَلَكُمۡ فِيهَا مَا تَشۡتَهِيٓ أَنفُسُكُمۡ وَلَكُمۡ فِيهَا مَا تَدَّعُونَ
Àwa ni ọ̀rẹ́ yín nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní ọ̀run. Ohun tí ẹ̀mí yín ń fẹ́ ti wà fún yín nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún sì ti wà nínú rẹ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
نُزُلٗا مِّنۡ غَفُورٖ رَّحِيمٖ
Ó jẹ́ n̄ǹkan ìgbàlejò (fún yín) láti ọ̀dọ̀ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمَنۡ أَحۡسَنُ قَوۡلٗا مِّمَّن دَعَآ إِلَى ٱللَّهِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا وَقَالَ إِنَّنِي مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ
Níbi ọ̀rọ̀ sísọ, ta ni ó dára ju ẹni tí ó pèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ṣe iṣẹ́ rere, tí ó sì sọ pé: “Dájúdájú èmí wà nínú àwọn mùsùlùmí?”[1]
[1] Kò sí ẹni tí ó dára jù ú lọ
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَا تَسۡتَوِي ٱلۡحَسَنَةُ وَلَا ٱلسَّيِّئَةُۚ ٱدۡفَعۡ بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ فَإِذَا ٱلَّذِي بَيۡنَكَ وَبَيۡنَهُۥ عَدَٰوَةٞ كَأَنَّهُۥ وَلِيٌّ حَمِيمٞ
Rere àti aburú kò dọ́gba. Fi èyí tí ó dára jùlọ dènà (aburú).[1] Nígbà náà ni ẹni tí ọ̀tá wà láààrin ìwọ àti òun máa dà bí ọ̀rẹ́ alásùn-únmọ́ pẹ́kípẹ́kí.
[1] Fífi rere dènà aburú ni ṣíṣe sùúrù pẹ̀lú ẹni tí ó ń bínú sí wa, ṣíṣe rere sí ẹni tí ó ń ṣe aburú sí wa, kíkí ẹni tí ó ń yàn wá lódì, ṣíṣe àtẹ̀mọ́ra pẹ̀lú ẹni tí ó ń hùwà àìmọ̀kan sí wa, wíwo ẹni tí ó ń ṣépè fún wa níran, wíwo ẹni tí ó ń bú wa níran àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَمَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ذُو حَظٍّ عَظِيمٖ
A ku n yín) sìn títí di ọjọá hu pátápátá.n ní Ọjọ́ Àjíǹde.́ wọn gbàgbé Allāhu.ò níí fún ẹnì kan ní (ìwà rere yìí) àfi àwọn tó ṣe sùúrù. A kò níí fún ẹnì kan sẹ́ àfi olórí-ire ńlá.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِمَّا يَنزَغَنَّكَ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ نَزۡغٞ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
Àti pé tí èròkérò kan láti ọ̀dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n bá fẹ́ ṣẹ́ ọ lórí (kúrò níbi ìwà rere yìí), sádi Allāhu (fi Allāhu wá ìṣọ́rí). Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِ ٱلَّيۡلُ وَٱلنَّهَارُ وَٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُۚ لَا تَسۡجُدُواْ لِلشَّمۡسِ وَلَا لِلۡقَمَرِ وَٱسۡجُدُواْۤ لِلَّهِۤ ٱلَّذِي خَلَقَهُنَّ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni òru, ọ̀sán, òòrùn àti òṣùpá. Ẹ kò gbọ́dọ̀ forí kanlẹ̀ fún òòrùn àti òṣùpá. Ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tí Ó dá wọn, tí ẹ̀yin bá jẹ́ ẹni tó ń jọ́sìn fún Òun nìkan ṣoṣo.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَإِنِ ٱسۡتَكۡبَرُواْ فَٱلَّذِينَ عِندَ رَبِّكَ يُسَبِّحُونَ لَهُۥ بِٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَهُمۡ لَا يَسۡـَٔمُونَ۩
Tí wọ́n bá sì ṣègbéraga, àwọn tó wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní alẹ́ àti ní ọ̀sán; wọn kò sì kágara.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنَّكَ تَرَى ٱلۡأَرۡضَ خَٰشِعَةٗ فَإِذَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهَا ٱلۡمَآءَ ٱهۡتَزَّتۡ وَرَبَتۡۚ إِنَّ ٱلَّذِيٓ أَحۡيَاهَا لَمُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰٓۚ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó talẹ̀ jí, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا لَا يَخۡفَوۡنَ عَلَيۡنَآۗ أَفَمَن يُلۡقَىٰ فِي ٱلنَّارِ خَيۡرٌ أَم مَّن يَأۡتِيٓ ءَامِنٗا يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ ٱعۡمَلُواْ مَا شِئۡتُمۡ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ
Dájúdájú àwọn tó ń darí àwọn āyah Wa kọ ọ̀nà òdì,[1] wọn kò pamọ́ fún Wa. Ṣé ẹni tí wọ́n máa jù sínú Iná l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó máa wá ní olùfàyàbalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde? Ẹ máa ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
[1] Nínú dídarí àwọn āyah al-Ƙur’ān kọ ọ̀nà òdì ni fífún āyah kan ní ìtúmọ̀ òdì, fífi āyah kan tako āyah mìíràn, lílo āyah kan ní àyè tí kò jẹmọ́ ọn, fífi āyah kan ṣe ẹ̀fẹ̀, ṣíṣe àtakò sí āyah kan, pípa ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān tì láti tẹ̀lé ìròrí, ìṣe àti àṣà ìgbà-àìmọ̀kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِٱلذِّكۡرِ لَمَّا جَآءَهُمۡۖ وَإِنَّهُۥ لَكِتَٰبٌ عَزِيزٞ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Tírà Ìrántí náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) nígbà tí ó dé bá wọn (ẹni ìparun ni wọ́n.) Dájúdájú òhun mà ni Tírà tó lágbára.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
لَّا يَأۡتِيهِ ٱلۡبَٰطِلُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَلَا مِنۡ خَلۡفِهِۦۖ تَنزِيلٞ مِّنۡ حَكِيمٍ حَمِيدٖ
Ìbàjẹ́ kò níí kàn án láti iwájú rẹ̀ àti láti ẹ̀yìn rẹ̀.[1] Ìmísí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Ẹlẹ́yìn.
[1] Ìyẹn ni pé, kò sí tírà sánmọ̀ kan tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé irọ́ wà nínú al-Ƙur’ān ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀. Kò sì wulẹ̀ níí sí tírà kan kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀ láti sánmọ̀, áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa pe al-Ƙur’ān ní irọ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
مَّا يُقَالُ لَكَ إِلَّا مَا قَدۡ قِيلَ لِلرُّسُلِ مِن قَبۡلِكَۚ إِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغۡفِرَةٖ وَذُو عِقَابٍ أَلِيمٖ
Wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan sí ọ bí kò ṣe ohun tí wọ́n ti sọ sí àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú rẹ. Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Ó sì ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro (lọ́dọ̀).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَوۡ جَعَلۡنَٰهُ قُرۡءَانًا أَعۡجَمِيّٗا لَّقَالُواْ لَوۡلَا فُصِّلَتۡ ءَايَٰتُهُۥٓۖ ءَا۬عۡجَمِيّٞ وَعَرَبِيّٞۗ قُلۡ هُوَ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ هُدٗى وَشِفَآءٞۚ وَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ فِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٞ وَهُوَ عَلَيۡهِمۡ عَمًىۚ أُوْلَٰٓئِكَ يُنَادَوۡنَ مِن مَّكَانِۭ بَعِيدٖ
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe al-Ƙur’ān ní n̄ǹkan kíké ní èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá ni, wọn ìbá wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n ṣe àlàyé àwọn āyah rẹ̀?” Báwo ni al-Ƙur’ān ṣe lè jẹ́ èdè mìíràn (yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá), nígbà tí Ànábì (Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) jẹ́ Lárúbáwá? Sọ pé: “Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìwòsàn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Àwọn tí kò sì gbàgbọ́, èdídí wà nínú etí wọn ni. Fọ́júǹǹfọ́jú sì wà nínú ojú wọn sí (òdodo al-Ƙur’ān). Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n sì ń pè (síbi òdodo al-Ƙur’ān) láti àyè tó jìnnà.[1]
[1] Ìyẹn ni pé, wọ́n ti sọnù jìnnà. Nítorí náà, wọn kò lè gbọ́ ìpè òdodo láti ọ̀nà jíjìn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَٱخۡتُلِفَ فِيهِۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ
A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa-ẹnu sí i. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ́ kan tí ó ti ṣíwájú ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, A ìbá ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n tún wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa al-Ƙur’ān.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
مَّنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ أَسَآءَ فَعَلَيۡهَاۗ وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّٰمٖ لِّلۡعَبِيدِ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
۞ إِلَيۡهِ يُرَدُّ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِۚ وَمَا تَخۡرُجُ مِن ثَمَرَٰتٖ مِّنۡ أَكۡمَامِهَا وَمَا تَحۡمِلُ مِنۡ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلۡمِهِۦۚ وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ أَيۡنَ شُرَكَآءِي قَالُوٓاْ ءَاذَنَّٰكَ مَا مِنَّا مِن شَهِيدٖ
Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò máa dá ìmọ̀ Àkókò náà padà sí. Kò sí èso kan tí ó máa jáde nínú apó rẹ̀, obìnrin kan kò sì níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Ó sì máa pè wọ́n pé: “Ibo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi (tí ẹ jọ́sìn fún) wà?”[1] Wọ́n á wí pé: “Àwa ń jẹ́ kí O mọ̀ pé kò sí olùjẹ́rìí kan nínú wa (tí ó máa jẹ́rìí pé, O ní akẹgbẹ́.)”
[1] Allāhu kò ní akẹgbẹ́ ẹyọ kan áḿbọ̀sìbọ́sí àwọn akẹgbẹ́. Àmọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ló sọ àwọn òrìṣà wọn di akẹgbẹ́ Allāhu. Ìpè àbùkù àti ìpè ẹ̀sín ni èyí máa jẹ́ fún àwọn abọ̀rìṣà àti àwọn òrìṣà wọn ní ọjọ́ ìpè náà, ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَدۡعُونَ مِن قَبۡلُۖ وَظَنُّواْ مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٖ
Ohun tí wọ́n ń pè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.[1] Wọ́n sì mọ̀ ní àmọ̀dájú pé, kò sí ibùsásí kan fún àwọn.
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:24.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
لَّا يَسۡـَٔمُ ٱلۡإِنسَٰنُ مِن دُعَآءِ ٱلۡخَيۡرِ وَإِن مَّسَّهُ ٱلشَّرُّ فَيَـُٔوسٞ قَنُوطٞ
Ènìyàn kò kó ṣúṣú níbi àdúà (láti tọrọ) oore. Tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù, olùjákànmùná.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَئِنۡ أَذَقۡنَٰهُ رَحۡمَةٗ مِّنَّا مِنۢ بَعۡدِ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُ لَيَقُولَنَّ هَٰذَا لِي وَمَآ أَظُنُّ ٱلسَّاعَةَ قَآئِمَةٗ وَلَئِن رُّجِعۡتُ إِلَىٰ رَبِّيٓ إِنَّ لِي عِندَهُۥ لَلۡحُسۡنَىٰۚ فَلَنُنَبِّئَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِمَا عَمِلُواْ وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنۡ عَذَابٍ غَلِيظٖ
Dájúdájú tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Wa lẹ́yìn aburú tí ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: “Èyí ni tèmi. Èmi kò sì ní àmọ̀dájú pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé dájúdájú tí Wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú rere tún wà fún mi ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.” Dájúdájú Àwa yóò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú A sì máa fún wọn ní ìyà tó nípọn tọ́ wò.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِذَآ أَنۡعَمۡنَا عَلَى ٱلۡإِنسَٰنِ أَعۡرَضَ وَنَـَٔا بِجَانِبِهِۦ وَإِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ فَذُو دُعَآءٍ عَرِيضٖ
Àti pé nígbà tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò ní ọ̀dọ̀ Wa). Ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, nígbà náà l’ó máa di aládùáà rẹgẹdẹ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كَانَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ ثُمَّ كَفَرۡتُم بِهِۦ مَنۡ أَضَلُّ مِمَّنۡ هُوَ فِي شِقَاقِۭ بَعِيدٖ
Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, lẹ́yìn náà tí ẹ ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ (ṣé ẹ̀yin kò ti wà nínú ìyapa bí?)” Ta l’ó ṣìnà ju ẹni tí ó wà nínú ìyapa tó jìnnà (sí òdodo)!
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
سَنُرِيهِمۡ ءَايَٰتِنَا فِي ٱلۡأٓفَاقِ وَفِيٓ أَنفُسِهِمۡ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَهُمۡ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّۗ أَوَلَمۡ يَكۡفِ بِرَبِّكَ أَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ
A óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan?
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أَلَآ إِنَّهُمۡ فِي مِرۡيَةٖ مِّن لِّقَآءِ رَبِّهِمۡۗ أَلَآ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءٖ مُّحِيطُۢ
Gbọ́, dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìpàdé Olúwa wọn. Gbọ́, dájúdájú Allāhu yí gbogbo n̄ǹkan ká.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
 
ការបកប្រែអត្ថន័យ ជំពូក​: ហ្វូសស៊ីឡាត់
មាតិកានៃជំពូក លេខ​ទំព័រ
 
ការបកប្រែអត្ថន័យនៃគម្ពីរគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល - មាតិកានៃការបកប្រែ

ការបកប្រែដោយលោក អាពូ​ រ៉ហុីម៉ះ​ មុីកាអុីល​ អៃក្វីនី។

បិទ