Check out the new design

ការបកប្រែអត្ថន័យនៃគម្ពីរគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល * - មាតិកានៃការបកប្រែ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ការបកប្រែអត្ថន័យ ជំពូក​: អាន់ណះល៍   វាក្យខណ្ឌ:

An-Nah'l

أَتَىٰٓ أَمۡرُ ٱللَّهِ فَلَا تَسۡتَعۡجِلُوهُۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Àṣẹ Allāhu dé tán. Ẹ ma wulẹ̀ wá a pẹ̀lú ìkánjú. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
يُنَزِّلُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ بِٱلرُّوحِ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦٓ أَنۡ أَنذِرُوٓاْ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱتَّقُونِ
(Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۚ تَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِن نُّطۡفَةٖ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٞ مُّبِينٞ
Ó dá ènìyàn láti inú àtọ̀. (Ènìyàn) sì di olùjiyàn pọ́nńbélé (nípa Àjíǹde).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱلۡأَنۡعَٰمَ خَلَقَهَاۖ لَكُمۡ فِيهَا دِفۡءٞ وَمَنَٰفِعُ وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ
Àwọn ẹran-ọ̀sìn, Ó ṣẹ̀dá wọn (fún yín). Aṣọ òtútù àti àwọn àǹfààní (mìíràn) ń bẹ fún yín lára wọn. Àti pé ẹ̀ ń jẹ nínú wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَكُمۡ فِيهَا جَمَالٌ حِينَ تُرِيحُونَ وَحِينَ تَسۡرَحُونَ
Ọ̀ṣọ́ tún ń bẹ fún yín lára wọn nígbà tí ẹ bá ń dà wọ́n lọ (sí ilé wọn) àti nígbà tí ẹ bá ń kó wọn jáde lọ jẹko.[1]
[1] Èyí ni pé, dída ẹran-ọ̀sìn lọ bọ̀, ó jẹ́ ọ̀ṣọ́ fún olówó rẹ̀ fún wí pé àwọn ènìyàn yóò mọ olówó ẹran-ọ̀sìn sí ẹni tí àṣírí rẹ̀ bò tàbí ọlọ́rọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَتَحۡمِلُ أَثۡقَالَكُمۡ إِلَىٰ بَلَدٖ لَّمۡ تَكُونُواْ بَٰلِغِيهِ إِلَّا بِشِقِّ ٱلۡأَنفُسِۚ إِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ
Wọ́n sì ń ru àwọn ẹrù yín tó wúwo lọ sí ìlú kan tí ẹ kò lè dé àfi pẹ̀lú wàhálà ẹ̀mí. Dájúdájú Olúwa yín mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱلۡخَيۡلَ وَٱلۡبِغَالَ وَٱلۡحَمِيرَ لِتَرۡكَبُوهَا وَزِينَةٗۚ وَيَخۡلُقُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ
(Ó ṣẹ̀dá) ẹṣin, ìbaaka àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ nítorí kí ẹ lè gùn wọ́n. (Wọ́n tún jẹ́) ọ̀ṣọ́. Ó tún ń ṣẹ̀dá ohun tí ẹ kò mọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَعَلَى ٱللَّهِ قَصۡدُ ٱلسَّبِيلِ وَمِنۡهَا جَآئِرٞۚ وَلَوۡ شَآءَ لَهَدَىٰكُمۡ أَجۡمَعِينَ
Allāhu l’Ó ń ṣàlàyé (’Islām) ọ̀nà tààrà. Àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wíwọ́ tún wà (lọ́tọ̀)[1]. Tí Ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìbá tọ́ gbogbo yín sí ọ̀nà (ẹ̀sìn ’Islām).
[1] Àwọn ọ̀nà wíwọ́ ni ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà, ẹ̀sìn yẹhudi àti ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗۖ لَّكُم مِّنۡهُ شَرَابٞ وَمِنۡهُ شَجَرٞ فِيهِ تُسِيمُونَ
Òun ni Ẹni tó ń sọ omi kalẹ̀ (fún yín) láti sánmọ̀. Mímu wà fún yín nínú rẹ̀. Igi ewéko tún ń wù jáde láti inú rẹ̀, tí ẹ fi ń bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
يُنۢبِتُ لَكُم بِهِ ٱلزَّرۡعَ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلنَّخِيلَ وَٱلۡأَعۡنَٰبَ وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
(Allāhu) tún ń fi (omi yìí) hu àwọn irúgbìn, igi òróró zaetūn, igi dàbínù, igi àjàrà àti gbogbo àwọn èso (yòókù) jáde fún yín. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ وَٱلنُّجُومُ مُسَخَّرَٰتُۢ بِأَمۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
Ó rọ òru, ọ̀sán, òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fún yín pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمَا ذَرَأَ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهُۥٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَذَّكَّرُونَ
Àti ohun tí Ó tún ṣẹ̀dá rẹ̀ fún yín lórí ilẹ̀, tí àwọn àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń lo ìrántí.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَهُوَ ٱلَّذِي سَخَّرَ ٱلۡبَحۡرَ لِتَأۡكُلُواْ مِنۡهُ لَحۡمٗا طَرِيّٗا وَتَسۡتَخۡرِجُواْ مِنۡهُ حِلۡيَةٗ تَلۡبَسُونَهَاۖ وَتَرَى ٱلۡفُلۡكَ مَوَاخِرَ فِيهِ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Òun ni Ẹni tí Ó rọ odò nítorí kí ẹ lè jẹ ẹran (ẹja) tútù àti nítorí kí ẹ lè mú n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ tí ẹ óò máa wọ̀ sára jáde láti inú (odò), - o sì máa rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí yóò máa la ojú omi kọjá lọ bọ̀ - àti nítorí kí ẹ lè wá nínú àwọn oore àjùlọ Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَأَلۡقَىٰ فِي ٱلۡأَرۡضِ رَوَٰسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمۡ وَأَنۡهَٰرٗا وَسُبُلٗا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ
Ó sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi sórí ilẹ̀ kí ó má baà mì mọ yín lẹ́sẹ̀ àti àwọn odò àti àwọn ojú-ọ̀nà nítorí kí ẹ lè dá ojú ọ̀nà mọ̀;
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَعَلَٰمَٰتٖۚ وَبِٱلنَّجۡمِ هُمۡ يَهۡتَدُونَ
àti àwọn àmì òpópónà (fún ìtọ́sọ́nà ìrìn ọ̀sán). Wọ́n tún ń fi ìràwọ̀ dá ojú ọ̀nà mọ̀ (lálẹ́).[1]
[1] Àwọn n̄ǹkan tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - dá fún dídá ojú ọ̀nà mọ̀ wọ̀nyí dúró fún rírína rí ojú ọ̀nà, yálà ní alẹ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tàbí ní ọ̀sán pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ òòrùn àti àwọn atọ́ka òpópónà.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أَفَمَن يَخۡلُقُ كَمَن لَّا يَخۡلُقُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá dà bí ẹni tí kò dá ẹ̀dá bí? Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِن تَعُدُّواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ لَا تُحۡصُوهَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ
Tí ẹ bá ṣòǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú Allāhu mà ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعۡلِنُونَ
Àti pé Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ
Àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu; wọn kò lè dá kiní kan. Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أَمۡوَٰتٌ غَيۡرُ أَحۡيَآءٖۖ وَمَا يَشۡعُرُونَ أَيَّانَ يُبۡعَثُونَ
Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.[1] Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò jí wọn dìde (nínú sàréè).
[1] Allāhu pe àwọn òrìṣà ní òkú nítorí pé, ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú, ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, ẹni tí kò lè ríran, ẹni tí kò lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́ ni ipò tí gbogbo ère òrìṣà wà.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۚ فَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ قُلُوبُهُم مُّنكِرَةٞ وَهُم مُّسۡتَكۡبِرُونَ
Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àmọ́ àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni ọkàn wọn takò ó, tí wọ́n sì ń ṣègbéraga.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
لَا جَرَمَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡتَكۡبِرِينَ
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِذَا قِيلَ لَهُم مَّاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡ قَالُوٓاْ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ni.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
لِيَحۡمِلُوٓاْ أَوۡزَارَهُمۡ كَامِلَةٗ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَمِنۡ أَوۡزَارِ ٱلَّذِينَ يُضِلُّونَهُم بِغَيۡرِ عِلۡمٍۗ أَلَا سَآءَ مَا يَزِرُونَ
(Wọ́n sọ bẹ́ẹ̀) nítorí kí wọ́n lè ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ní pípé pérépéré ní Ọjọ́ Àjíǹde àti (nítorí kí wọ́n lè rù) nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n ń ṣì lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Gbọ́, ohun tí wọn yóò rù ní ẹ̀ṣẹ̀, ó burú.[1]
[1] Kíyè sí i! Kò sí ìtakora láààrin āyah yìí àti sūrah an-Najm; 53:38. Āyah àkọ́kọ́ ń sọ nípa ìpín ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa wà fún onísábàbí iṣẹ́-aburú àti onísábàbí ìṣìnà. Ìyẹn ni pé, bí ìyà ṣe wà fún oníṣẹ́-aburú bẹ́ẹ̀ náà ni ìyà wà fún onísábàbí rẹ̀. Ní ti āyah ti sūrah an-Najm, ò ń sọ nípa bí kò ṣe níí sí àǹfààní fún ẹnikẹ́ni láti gbé àpapọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lọ́rùn rẹ̀ fún ẹlòmíìràn ní Ọjọ́ ẹ̀san. Nítorí náà, àròpọ̀ iṣẹ́ tí ẹ̀dá ṣe àti iṣẹ́ tí ó ṣe sábàbí rẹ̀ ló máa wà lọ́rùn rẹ̀, yálà ó jẹ́ iṣẹ́ rere tàbí iṣẹ́ aburú. Kò sì níí rí alábàárù-ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ ọrùn rẹ̀. Ẹ tún wo sūrah al-‘ankabūt; 29:12 àti 13.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
قَدۡ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَأَتَى ٱللَّهُ بُنۡيَٰنَهُم مِّنَ ٱلۡقَوَاعِدِ فَخَرَّ عَلَيۡهِمُ ٱلسَّقۡفُ مِن فَوۡقِهِمۡ وَأَتَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ
Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú déte. Allāhu sì da ilé wọn wó látibi àwọn òpó ilé. Òrùlé sì wó lù wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn. Àti pé ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ثُمَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يُخۡزِيهِمۡ وَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تُشَٰٓقُّونَ فِيهِمۡۚ قَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ إِنَّ ٱلۡخِزۡيَ ٱلۡيَوۡمَ وَٱلسُّوٓءَ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde (Allāhu) yóò yẹpẹrẹ wọn. Ó sì máa sọ pé: “Ibo ni àwọn (tí ẹ sọ di) akẹgbẹ́ Mi wà, àwọn tí ẹ tìtorí wọn yapa (ọ̀rọ̀ Mi)?” Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ẹ̀sìn yó sì sọ pé: “Dájúdájú àbùkù àti aburú ọjọ́ òní wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ ظَالِمِيٓ أَنفُسِهِمۡۖ فَأَلۡقَوُاْ ٱلسَّلَمَ مَا كُنَّا نَعۡمَلُ مِن سُوٓءِۭۚ بَلَىٰٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
(Àwọn ni) àwọn tí mọlāika ń pa nígbà tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn lọ́wọ́. Ní àsìkò yìí ni wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (wọ́n sì wí pé): “Àwa kò ṣe iṣẹ́ aburú kan kan.” Bẹ́ẹ̀ ni (irọ́ lẹ́pa)! Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَلَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ
Nítorí náà, ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà Iná lọ, olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
۞ وَقِيلَ لِلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ مَاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡۚ قَالُواْ خَيۡرٗاۗ لِّلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٞۚ وَلَدَارُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞۚ وَلَنِعۡمَ دَارُ ٱلۡمُتَّقِينَ
Wọ́n sọ fún àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Rere ni.” Rere ti wà fún àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn lóore jùlọ. Àti pé dájúdájú ilé àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) dára.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
جَنَّٰتُ عَدۡنٖ يَدۡخُلُونَهَا تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ لَهُمۡ فِيهَا مَا يَشَآءُونَۚ كَذَٰلِكَ يَجۡزِي ٱللَّهُ ٱلۡمُتَّقِينَ
Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra 'Adn ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń san ẹ̀san rere fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ طَيِّبِينَ يَقُولُونَ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمُ ٱدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Àwọn tí mọlāika ń pa, nígbà tí wọ́n ń ṣe rere lọ́wọ́, (àwọn mọlāika) ń sọ pé: “Àlàáfíà fún yín. Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ أَوۡ يَأۡتِيَ أَمۡرُ رَبِّكَۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ
Ṣé wọ́n ń retí ohun kan yàtọ̀ sí pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí àṣẹ Olúwa rẹ dé? Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ti ṣe. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَأَصَابَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا عَمِلُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Nítorí náà, àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ لَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا عَبَدۡنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖ نَّحۡنُ وَلَآ ءَابَآؤُنَا وَلَا حَرَّمۡنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ فَهَلۡ عَلَى ٱلرُّسُلِ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Àwọn tí wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́ yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fẹ́ ni àwa ìbá tí jọ́sìn fún kiní kan lẹ́yìn Rẹ̀, àwa àti àwọn bàbá wa. Bákàn náà, àwa ìbá tí ṣe kiní kan ní èèwọ̀ lẹ́yìn Rẹ̀.” Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ti ṣe. Ǹjẹ́ ojúṣe kan wà fún àwọn Òjíṣẹ́ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَقَدۡ بَعَثۡنَا فِي كُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱجۡتَنِبُواْ ٱلطَّٰغُوتَۖ فَمِنۡهُم مَّنۡ هَدَى ٱللَّهُ وَمِنۡهُم مَّنۡ حَقَّتۡ عَلَيۡهِ ٱلضَّلَٰلَةُۚ فَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ
Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Nítorí náà, ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ sì wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn tó pé àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́ ṣe rí?
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِن تَحۡرِصۡ عَلَىٰ هُدَىٰهُمۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَن يُضِلُّۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّٰصِرِينَ
Tí o bá ń ṣojú kòkòrò sí ìmọ̀nà wọn, dájúdájú Allāhu, ẹni tí Ó bá ṣì lọ́nà, kò níí mọ̀nà,[1] kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan kan fún wọn.
[1] Bákan náà ni ìtúmọ̀ gbólóhùn yìí àti tinú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:186.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَا يَبۡعَثُ ٱللَّهُ مَن يَمُوتُۚ بَلَىٰ وَعۡدًا عَلَيۡهِ حَقّٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: “Allāhu kò níí gbé ẹni tí ó kú dìde.” Bẹ́ẹ̀ ni, (àjíǹde jẹ́) àdéhùn òdodo lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò mọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
لِيُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِي يَخۡتَلِفُونَ فِيهِ وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ كَانُواْ كَٰذِبِينَ
(Allāhu yóò gbé ẹ̀dá dìde) nítorí kí Ó lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí fún wọn àti nítorí kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lè mọ̀ pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ òpùrọ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّمَا قَوۡلُنَا لِشَيۡءٍ إِذَآ أَرَدۡنَٰهُ أَن نَّقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Ọ̀rọ̀ Wa fún kiní kan nígbà tí A bá gbèrò rẹ̀ ni pé, A máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ فِي ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا ظُلِمُواْ لَنُبَوِّئَنَّهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗۖ وَلَأَجۡرُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَكۡبَرُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ
Àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ti Allāhu, lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti ṣàbòsí sí wọn, dájúdájú Àwa yóò wá ibùgbé rere fún wọn. Ẹ̀san Ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé (àwọn tí kò ṣe hijrah) mọ̀ ni.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ
(Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù, wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِمۡۖ فَسۡـَٔلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلذِّكۡرِ إِن كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ
A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.[1]
[1] “ahlu-ththikr” (ìtúmọ̀ “àwọn oníràn-ántí / àwọn tí A sọ ìrántí kalẹ̀ fún).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِۗ وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلذِّكۡرَ لِتُبَيِّنَ لِلنَّاسِ مَا نُزِّلَ إِلَيۡهِمۡ وَلَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ
(A fi) àwọn ẹ̀rí tó yanjú àti ìpín-ìpín Tírà (rán wọn níṣẹ́). Àti pé A sọ tírà Ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn[1] àti nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.
[1] Orúkọ tí wọ́n ń pe àlàyé tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe lórí al-Ƙur’ān ni “hadīth nabawiy” tàbí “sunnatu-rrọsūl” - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - . Ìmísí ni òhun náà nítorí pé, kì í fi ìfẹ́-inú rẹ̀ sọ̀rọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أَفَأَمِنَ ٱلَّذِينَ مَكَرُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن يَخۡسِفَ ٱللَّهُ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضَ أَوۡ يَأۡتِيَهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ
Ṣé àwọn tó dá ète aburú fi ọkàn balẹ̀ pé Allāhu kò lè mú ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ni, tàbí pé ìyà kò lè dé bá wọn láti àyè tí wọn kò ti níí fura?
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أَوۡ يَأۡخُذَهُمۡ فِي تَقَلُّبِهِمۡ فَمَا هُم بِمُعۡجِزِينَ
Tàbí (Allāhu) kò lè gbá wọn mú lórí ìrìnkè-rindò wọn ni? Wọn kò sì níí mórí bọ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أَوۡ يَأۡخُذَهُمۡ عَلَىٰ تَخَوُّفٖ فَإِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٌ
Tàbí (Allāhu) kò lè máa gbá wọn mú díẹ̀díẹ̀ ni?[1] Nítorí náà, dájúdájú Olúwa yin má ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́.
[1] “‘Alā takawwuf” nínú āyah yìí tún túmọ̀ sí pé, “Tàbí (Allāhu) kò lè máa gbá wọn mú pẹ̀lú ẹ̀rù tí ó máa ti wà lára wọn nípa irú ìyà wo ni Allāhu máa fi jẹ wọ́n, tàbí irú àdánwò wo ni Ó máa dẹ sí wọn.”.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَىٰ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ يَتَفَيَّؤُاْ ظِلَٰلُهُۥ عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَٱلشَّمَآئِلِ سُجَّدٗا لِّلَّهِ وَهُمۡ دَٰخِرُونَ
Àti pé ṣé wọn kò wòye sí gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀, tí òòji rẹ̀ ń tẹ̀ sí ọ̀tún àti òsì[1] tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún Allāhu; tí wọ́n sì ń yẹpẹrẹ ara wọn (fún Un)?
[1] Ìyẹn ni pé, ní àárọ̀ láààrin ìgbà tí òòrùn bá yọ ní ìlà òòrùn títí di àsìkò òòrùn kàntàrí, òòji n̄ǹkan máa tẹ̀ sí agbègbè ìwọ̀ òòrùn ní orí ilẹ̀. Bákan náà, níkété tí òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí òòrùn máa wọ̀ ní ìwọ̀ òòrùn, òòji n̄ǹkan máa tẹ̀ sí agbègbè ìlà òòrùn ní orí ilẹ̀. Wàyí o, ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, ó sọ pé, “Títẹ̀ tí òòji gbogbo n̄ǹkan ń tẹ̀ sí ọ̀tún àti òsì ló ń dúró fún ìforíkanlẹ̀ wọn fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - . (Ƙurtubiy)
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلِلَّهِۤ يَسۡجُدُۤ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ مِن دَآبَّةٖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَهُمۡ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ
Allāhu sì ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ní n̄ǹkan abẹ̀mí àti àwọn mọlāika ń forí kanlẹ̀ fún. Wọn kò sì ṣègbéraga.[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah ar-Ra‘d; 13:15.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
يَخَافُونَ رَبَّهُم مِّن فَوۡقِهِمۡ وَيَفۡعَلُونَ مَا يُؤۡمَرُونَ۩
Wọ́n ń páyà Olúwa wọn tó ń bẹ lókè wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí À ń pa láṣẹ fún wọn.[1]
[1] Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:18 àti sūrah al-Mujādilah; 58:7.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
۞ وَقَالَ ٱللَّهُ لَا تَتَّخِذُوٓاْ إِلَٰهَيۡنِ ٱثۡنَيۡنِۖ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَإِيَّٰيَ فَٱرۡهَبُونِ
Allāhu sọ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ọlọ́hun méjì. Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Nítorí náà, Èmi (nìkan) ni kí ẹ bẹ̀rù.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَهُ ٱلدِّينُ وَاصِبًاۚ أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَتَّقُونَ
TiRẹ̀ sì ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. TiRẹ̀ sì ni (àfọ̀mọ́) ẹ̀sìn títí láéláé[1] Nítorí náà, ṣé (n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí Allāhu ni ẹ̀yin yóò máa bẹ̀rù ni?
[1] Ìyẹn ni pé, Allāhu nìkan ṣoso ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمَا بِكُم مِّن نِّعۡمَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ ثُمَّ إِذَا مَسَّكُمُ ٱلضُّرُّ فَإِلَيۡهِ تَجۡـَٔرُونَ
Ohunkóhun tí ẹ ní nínú ìdẹ̀ra, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Lẹ́yìn náà, tí ọwọ́ ìnira bá tẹ̀ yín, Òun ni ẹ̀ ń ké pè (fún ìdáǹdè.)
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ثُمَّ إِذَا كَشَفَ ٱلضُّرَّ عَنكُمۡ إِذَا فَرِيقٞ مِّنكُم بِرَبِّهِمۡ يُشۡرِكُونَ
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá mú ìnira náà kúrò fún yín tán, nígbà náà ni apá kan nínú yín yó sì máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡۚ فَتَمَتَّعُواْ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ
nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn. Nítorí náà, ẹ máa gbádùn ǹsó. Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَيَجۡعَلُونَ لِمَا لَا يَعۡلَمُونَ نَصِيبٗا مِّمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡۗ تَٱللَّهِ لَتُسۡـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمۡ تَفۡتَرُونَ
Wọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò nímọ̀ nípa rẹ̀.[1] Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́.
[1] Ìyẹn ni pé, wọ́n ń pe àwọn n̄ǹkan kan ní n̄ǹkan òrìṣà bí àpẹ̀ẹrẹ, wọ́n ń pe àwọn ẹran kan ní ẹran òrìṣà, wọ́n sì ń fi àwọn kan rúbọ fún àwọn òrìṣà wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَيَجۡعَلُونَ لِلَّهِ ٱلۡبَنَٰتِ سُبۡحَٰنَهُۥ وَلَهُم مَّا يَشۡتَهُونَ
Wọ́n tún ń fi (bíbí) àwọn ọmọbìnrin lélẹ̀ fún Allāhu - Mímọ́ ni fún Un (kò bímọ). - Wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń fẹ́ lélẹ̀ fún tiwọn!
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِٱلۡأُنثَىٰ ظَلَّ وَجۡهُهُۥ مُسۡوَدّٗا وَهُوَ كَظِيمٞ
Nígbà tí wọ́n bá fún ọ̀kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú (pé ó bí) ọmọbìnrin, ojú rẹ̀ yóò di dúdú fún ìbànújẹ́, tí ó sì máa pa á mọ́ra.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
يَتَوَٰرَىٰ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ مِن سُوٓءِ مَا بُشِّرَ بِهِۦٓۚ أَيُمۡسِكُهُۥ عَلَىٰ هُونٍ أَمۡ يَدُسُّهُۥ فِي ٱلتُّرَابِۗ أَلَا سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ
Ó sì máa fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn nítorí ìró aburú tí wọ́n fún un. Ṣé ó máa gbà a mú ní n̄ǹkan àbùkù ni tàbí ó máa bò ó mọ́lẹ̀ láàyè? Ẹ gbọ́, ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú!
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
لِلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ مَثَلُ ٱلسَّوۡءِۖ وَلِلَّهِ ٱلۡمَثَلُ ٱلۡأَعۡلَىٰۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni àkàwé aburú. Ti Allāhu sì ni àkàwé tó ga jùlọ. Àti pé Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَوۡ يُؤَاخِذُ ٱللَّهُ ٱلنَّاسَ بِظُلۡمِهِم مَّا تَرَكَ عَلَيۡهَا مِن دَآبَّةٖ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗىۖ فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ لَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ سَاعَةٗ وَلَا يَسۡتَقۡدِمُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń gbá àwọn ènìyàn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn, ìbá tí ṣẹ́ abẹ̀mí kan kan kù sórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí lè sún un sẹ́yìn di àkókò kan, wọn kò sì níí lè sún un síwájú.”[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:34.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَيَجۡعَلُونَ لِلَّهِ مَا يَكۡرَهُونَۚ وَتَصِفُ أَلۡسِنَتُهُمُ ٱلۡكَذِبَ أَنَّ لَهُمُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ لَا جَرَمَ أَنَّ لَهُمُ ٱلنَّارَ وَأَنَّهُم مُّفۡرَطُونَ
Wọ́n ń fi (ọmọbìnrin) - n̄ǹkan tí wọn kórira - lélẹ̀ fún Allāhu. Ahọ́n wọn sì ń ròyìn irọ́ pé dájúdájú rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni tàwọn. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Iná ni tiwọn. Àti pé dájúdájú wọ́n máa pa wọ́n tì sínú rẹ̀ ni.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
تَٱللَّهِ لَقَدۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰٓ أُمَمٖ مِّن قَبۡلِكَ فَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ فَهُوَ وَلِيُّهُمُ ٱلۡيَوۡمَ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Allāhu fi ara Rẹ̀ búra,[1] dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. Nígbà náà, aṣ-Ṣaetọ̄n ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn; òun sì ni ọ̀rẹ́ wọn ní òní. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
[1] Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi Ara Rẹ̀ búra. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún Un láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Òun l’Ó ni Ara Rẹ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا لِتُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِي ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
A kò sọ Tírà náà kalẹ̀ fún ọ bí kò ṣe pé kí o lè ṣàlàyé fún wọn ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí;[1] ó sì jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 44.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱللَّهُ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ
Allāhu l’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì ń fi jí ilẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti kú. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń gbọ́rọ̀ (òdodo).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِنَّ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَنۡعَٰمِ لَعِبۡرَةٗۖ نُّسۡقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهِۦ مِنۢ بَيۡنِ فَرۡثٖ وَدَمٖ لَّبَنًا خَالِصٗا سَآئِغٗا لِّلشَّٰرِبِينَ
Dájúdájú àríwòye wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn, tí À ń fún yín mu nínú n̄ǹkan tó wà nínú rẹ̀, (èyí) tí ó ń jáde wá láti ààrin bọ́tọ inú agbẹ̀du àti ẹ̀jẹ̀. (Ó sì ń di) wàrà mímọ́ tó ń lọ tìnrín ní ọ̀fun àwọn tó ń mu ún.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَمِن ثَمَرَٰتِ ٱلنَّخِيلِ وَٱلۡأَعۡنَٰبِ تَتَّخِذُونَ مِنۡهُ سَكَرٗا وَرِزۡقًا حَسَنًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
Àti pé láti ara àwọn èso dàbínù àti èso àjàrà ni ẹ ti ń ṣe ọtí[1] àti n̄ǹkan jíjẹ-mímu tó dára. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
[1] Ìyẹn ṣíwájú kí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - tó ṣe ọtí ní èèwọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:90.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَأَوۡحَىٰ رَبُّكَ إِلَى ٱلنَّحۡلِ أَنِ ٱتَّخِذِي مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتٗا وَمِنَ ٱلشَّجَرِ وَمِمَّا يَعۡرِشُونَ
Olúwa rẹ sì fi mọ kòkòrò oyin pé: “Mu ilé sínú àpáta, (mú un sínú) igi, (kí ó sì mú un) sínú ohun tí (àwọn ènìyàn) mọ ga.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ثُمَّ كُلِي مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ فَٱسۡلُكِي سُبُلَ رَبِّكِ ذُلُلٗاۚ يَخۡرُجُ مِنۢ بُطُونِهَا شَرَابٞ مُّخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهُۥ فِيهِ شِفَآءٞ لِّلنَّاسِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
Lẹ́yìn náà, jẹ lára gbogbo èso, kí o sì tọ àwọn ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ìtẹríba.” Ohun mímu tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn yóò máa jáde láti inú kòkòrò oyin. Ìwòsàn wà nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ ثُمَّ يَتَوَفَّىٰكُمۡۚ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرۡذَلِ ٱلۡعُمُرِ لِكَيۡ لَا يَعۡلَمَ بَعۡدَ عِلۡمٖ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٞ قَدِيرٞ
Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá yín. Lẹ́yìn náà, Ó ń gba ẹ̀mí yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá padà sí ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alágbára.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱللَّهُ فَضَّلَ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلرِّزۡقِۚ فَمَا ٱلَّذِينَ فُضِّلُواْ بِرَآدِّي رِزۡقِهِمۡ عَلَىٰ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَهُمۡ فِيهِ سَوَآءٌۚ أَفَبِنِعۡمَةِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ
Allāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Bẹ́ẹ̀, àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, wọn kì í fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, nítorí kí wọ́n má baà wà ní dọ́gban̄dọ́gba pẹ̀lú wọn níbi arísìkí![1] Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò?
[1] Àkàwé kan nìyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi lélẹ̀ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti pe làákàyè wọn sí ohun tí wọn kò lè gbà, àmọ́ tí wọ́n ń fi lọ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُم بَنِينَ وَحَفَدَةٗ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِۚ أَفَبِٱلۡبَٰطِلِ يُؤۡمِنُونَ وَبِنِعۡمَتِ ٱللَّهِ هُمۡ يَكۡفُرُونَ
Àti pé Allāhu ṣe àwọn ìyàwó fún yín láti ara yín. Ó fún yín ní àwọn ọmọ àti ọmọọmọ láti ara àwọn ìyàwó yín. Ó sì pèsè arísìkí fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ṣé irọ́ (ìyẹn, òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yó sì máa ṣàì moore sí?
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَمۡلِكُ لَهُمۡ رِزۡقٗا مِّنَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ شَيۡـٔٗا وَلَا يَسۡتَطِيعُونَ
Dípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò ní ìkápá arísìkí kan kan fún wọn nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; wọn kò sì lágbára (láti ṣe n̄ǹkan kan).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَلَا تَضۡرِبُواْ لِلَّهِ ٱلۡأَمۡثَالَۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ
Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn aláfijọ kan lélẹ̀ pé wọ́n jọ Allāhu. Dájúdájú Allāhu nímọ̀; ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
۞ ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا عَبۡدٗا مَّمۡلُوكٗا لَّا يَقۡدِرُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَمَن رَّزَقۡنَٰهُ مِنَّا رِزۡقًا حَسَنٗا فَهُوَ يُنفِقُ مِنۡهُ سِرّٗا وَجَهۡرًاۖ هَلۡ يَسۡتَوُۥنَۚ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí tó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí?[1] Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
[1] Ìyẹn ni pé, kò sí ẹgbẹ́ tàbí ìdọ́gba láààrin ẹni tí ó ní òmìnira tí ó lè dá n̄ǹkan ṣe àti ẹrú aláìlágbára tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا رَّجُلَيۡنِ أَحَدُهُمَآ أَبۡكَمُ لَا يَقۡدِرُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَهُوَ كَلٌّ عَلَىٰ مَوۡلَىٰهُ أَيۡنَمَا يُوَجِّههُّ لَا يَأۡتِ بِخَيۡرٍ هَلۡ يَسۡتَوِي هُوَ وَمَن يَأۡمُرُ بِٱلۡعَدۡلِ وَهُوَ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Allāhu tún fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ọkùnrin méjì kan, tí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ odi, tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe, tí ó tún jẹ́ wàhálà fún ọ̀gá rẹ̀ (nítorí pé) ibikíbi tí ó bá rán an lọ, kò níí mú oore kan bọ̀ (fún un láti ibẹ̀). Ṣé ó dọ́gba pẹ̀lú ẹni tí Ó ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, tí ó sì wà lójú ọ̀nà tààrà?[1]
[1] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èèwọ̀ ẹ̀sìn ni fún ẹ̀dá láti fi àkàwé àti àfijọ lélẹ̀ fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah 74, Allāhu lè fi àkàwé ara Rẹ̀ lélẹ̀ fún ẹ̀dá nítorí kí ẹ̀dá lè mọ̀ pé Allāhu tóbi jùlọ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلِلَّهِ غَيۡبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَمَآ أَمۡرُ ٱلسَّاعَةِ إِلَّا كَلَمۡحِ ٱلۡبَصَرِ أَوۡ هُوَ أَقۡرَبُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀rọ̀ Àkókò náà kò kúkú tayọ ìṣẹ́jú tàbí kí ó tún súnmọ́ julọ. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱللَّهُ أَخۡرَجَكُم مِّنۢ بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ شَيۡـٔٗا وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَٱلۡأَفۡـِٔدَةَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Allāhu l’Ó mu yín jáde láti inú ikùn àwọn ìyá yín nígbà tí ẹ̀yin kò tí ì dá n̄ǹkan kan mọ̀. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَى ٱلطَّيۡرِ مُسَخَّرَٰتٖ فِي جَوِّ ٱلسَّمَآءِ مَا يُمۡسِكُهُنَّ إِلَّا ٱللَّهُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Ṣé wọn kò wòye sí àwọn ẹyẹ tí A rọ̀ (fún fífò) nínú òfurufú (lábẹ́) sánmọ̀? Kò sí ẹni tó ń mú wọn dúró (sínú òfurufú) bí kò ṣe Allāhu. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۢ بُيُوتِكُمۡ سَكَنٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّن جُلُودِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ بُيُوتٗا تَسۡتَخِفُّونَهَا يَوۡمَ ظَعۡنِكُمۡ وَيَوۡمَ إِقَامَتِكُمۡ وَمِنۡ أَصۡوَافِهَا وَأَوۡبَارِهَا وَأَشۡعَارِهَآ أَثَٰثٗا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ
Allāhu ṣe ibùsinmi fún yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan tó fúyẹ́ fún yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn,[1] irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀.
[1] Ìtúmọ̀ “sūf” ni “irun àgùtàn”, "aswāf" jẹ́ "jam'u" ọ̀pọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّمَّا خَلَقَ ظِلَٰلٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡجِبَالِ أَكۡنَٰنٗا وَجَعَلَ لَكُمۡ سَرَٰبِيلَ تَقِيكُمُ ٱلۡحَرَّ وَسَرَٰبِيلَ تَقِيكُم بَأۡسَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُسۡلِمُونَ
Allāhu ṣe àwọn ibòji fún yín láti ara àwọn n̄ǹkan tí Ó dá. Ó ṣe àwọn ibùgbé fún yín láti ara àwọn àpáta. Ó tún ṣe àwọn aṣọ fún yín tó ń dáàbò bò yín lọ́wọ́ ooru àti àwọn aṣọ tó ń dáàbò bò yín lójú ogun yín.[1] Báyẹn l’Ó ṣe ń pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ le yín lórí nítorí kí ẹ lè jẹ́ mùsùlùmí.
[1] Àpẹ̀ẹrẹ aṣọ tó ń dáàbò bo ẹ̀dá lójú ogun ni ẹ̀wù irin tí kì í jẹ́ kí ọfà wọlé sínú ara. Àwọn aṣọ ààbò ogun wọ̀nyí kò túmọ̀ sí aṣọ òògùn bíi bàǹtẹ́ òògùn fún ààbò lójú ogun. Irúfẹ́ àwọn aṣọ òògùn wọ̀nyí jẹ́ èèwọ̀ ẹ̀sìn nítorí pé, wọn kò là níbi ṣíṣe ẹbọ àti wíwá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ àlùjànnú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lo irúfẹ́ aṣọ òògùn yìí sì ti sọ ara rẹ̀ di ọ̀ṣẹbọ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّمَا عَلَيۡكَ ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú ni ojúṣe tìrẹ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
يَعۡرِفُونَ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ ثُمَّ يُنكِرُونَهَا وَأَكۡثَرُهُمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Wọ́n mọ ìdẹ̀ra Allāhu, lẹ́yìn náà wọ́n ń takò ó. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni aláìmoore.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَيَوۡمَ نَبۡعَثُ مِن كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدٗا ثُمَّ لَا يُؤۡذَنُ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ
(Rántí) ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí kan dìde nínú gbogbo ìjọ (àwọn Ànábì), lẹ́yìn náà, A ò níí yọ̀ǹda (àròyé ṣíṣe) fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti padà ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلۡعَذَابَ فَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ
Nígbà tí àwọn tó ṣàbòsí bá rí Ìyà, nígbà náà, A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí lọ́ wọn lára láti wọ (inú Iná).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ شُرَكَآءَهُمۡ قَالُواْ رَبَّنَا هَٰٓؤُلَآءِ شُرَكَآؤُنَا ٱلَّذِينَ كُنَّا نَدۡعُواْ مِن دُونِكَۖ فَأَلۡقَوۡاْ إِلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلَ إِنَّكُمۡ لَكَٰذِبُونَ
Nígbà tí àwọn tó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ bá rí àwọn òrìṣà wọn, wọ́n á wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni àwọn òrìṣà wa tí à ń pè lẹ́yìn Rẹ.” Nígbà náà (àwọn òrìṣà) yóò ju ọ̀rọ̀ náà padà sí wọ́n pé: “Dájúdájú òpùrọ́ mà ni ẹ̀yin.”
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَأَلۡقَوۡاْ إِلَى ٱللَّهِ يَوۡمَئِذٍ ٱلسَّلَمَۖ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Wọ́n sì máa jura wọn sílẹ̀ fún Allāhu ní ọjọ́ yẹn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:24.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ زِدۡنَٰهُمۡ عَذَابٗا فَوۡقَ ٱلۡعَذَابِ بِمَا كَانُواْ يُفۡسِدُونَ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A ó ṣe àlékún ìyà lórí ìyà fún wọn ni nítorí pé wọ́n ń ṣèbàjẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَيَوۡمَ نَبۡعَثُ فِي كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدًا عَلَيۡهِم مِّنۡ أَنفُسِهِمۡۖ وَجِئۡنَا بِكَ شَهِيدًا عَلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِۚ وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ تِبۡيَٰنٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُسۡلِمِينَ
(Rántí) Ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí dìde fún ìjọ kọ̀ọ̀kan láààrin ara wọn, A sì máa mú ìwọ wá ní ẹlẹ́rìí fún àwọn wọ̀nyí. A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan,[1] ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:114.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
۞ إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُ بِٱلۡعَدۡلِ وَٱلۡإِحۡسَٰنِ وَإِيتَآيِٕ ذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَيَنۡهَىٰ عَنِ ٱلۡفَحۡشَآءِ وَٱلۡمُنكَرِ وَٱلۡبَغۡيِۚ يَعِظُكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ
Dájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). Ó sì ń kọ ìwà ìbàjẹ́, ohun burúkú àti rúkèrúdò. Ó ń ṣe wáàsí fún yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَأَوۡفُواْ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ إِذَا عَٰهَدتُّمۡ وَلَا تَنقُضُواْ ٱلۡأَيۡمَٰنَ بَعۡدَ تَوۡكِيدِهَا وَقَدۡ جَعَلۡتُمُ ٱللَّهَ عَلَيۡكُمۡ كَفِيلًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا تَفۡعَلُونَ
Kí ẹ sì mú àdéhùn Allāhu ṣẹ nígbà tí ẹ bá ṣe àdéhùn. Ẹ má ṣe tú ìbúra lẹ́yìn ìfirinlẹ̀ rẹ̀. Ẹ sì kúkú ti fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí lórí ara yín. Dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّتِي نَقَضَتۡ غَزۡلَهَا مِنۢ بَعۡدِ قُوَّةٍ أَنكَٰثٗا تَتَّخِذُونَ أَيۡمَٰنَكُمۡ دَخَلَۢا بَيۡنَكُمۡ أَن تَكُونَ أُمَّةٌ هِيَ أَرۡبَىٰ مِنۡ أُمَّةٍۚ إِنَّمَا يَبۡلُوكُمُ ٱللَّهُ بِهِۦۚ وَلَيُبَيِّنَنَّ لَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ
Kí ẹ sì má ṣe dà bí (obìnrin) èyí tí ó tú òwú dídì rẹ̀ palẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ lẹ́yìn tí ó tí dì í le. Ńṣe ni ẹ̀ ń lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín nítorí pé ìran kan pọ̀ ju ìran kan. Dájúdájú Allāhu ń dan yín wò pẹ̀lú rẹ̀ ni. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde Ó kúkú máa ṣàlàyé fún yín ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَلَتُسۡـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n Ó ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Dájúdájú wọ́n máa bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَا تَتَّخِذُوٓاْ أَيۡمَٰنَكُمۡ دَخَلَۢا بَيۡنَكُمۡ فَتَزِلَّ قَدَمُۢ بَعۡدَ ثُبُوتِهَا وَتَذُوقُواْ ٱلسُّوٓءَ بِمَا صَدَدتُّمۡ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَكُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Ẹ má ṣe lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín, nítorí kí ẹsẹ̀ yín má baà yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìdúróṣinṣin rẹ̀, àti nítorí kí ẹ má baà tọ́ ìyà burúkú wò nípa bí ẹ ṣe ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Ìyà ńlá yó sì wà fún yín.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَا تَشۡتَرُواْ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ ثَمَنٗا قَلِيلًاۚ إِنَّمَا عِندَ ٱللَّهِ هُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
Ẹ má ṣe ta àdéhùn Allāhu ní owó pọ́ọ́kú. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu, ó lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
مَا عِندَكُمۡ يَنفَدُ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ بَاقٖۗ وَلَنَجۡزِيَنَّ ٱلَّذِينَ صَبَرُوٓاْ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ yín máa tán. Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì máa wà títí láéláé. Dájúdájú A sì máa san àwọn tó ṣe sùúrù ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَنُحۡيِيَنَّهُۥ حَيَوٰةٗ طَيِّبَةٗۖ وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé tó dára. Dájúdájú A sì máa san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَإِذَا قَرَأۡتَ ٱلۡقُرۡءَانَ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ ٱلرَّجِيمِ
Nígbà tí o bá (fẹ́) ké al-Ƙur’ān, sá di Allāhu níbi (aburú) aṣ-Ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّهُۥ لَيۡسَ لَهُۥ سُلۡطَٰنٌ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ
Dájúdájú kò sí agbára kan fún un lórí àwọn tó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّمَا سُلۡطَٰنُهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ يَتَوَلَّوۡنَهُۥ وَٱلَّذِينَ هُم بِهِۦ مُشۡرِكُونَ
Ẹni tí (aṣ-Ṣaetọ̄n) lágbára lórí rẹ̀ ni àwọn tó ń mú un ní ọ̀rẹ́ àti àwọn tó sọ ọ́ di akẹgbẹ́ Allāhu.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِذَا بَدَّلۡنَآ ءَايَةٗ مَّكَانَ ءَايَةٖ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا يُنَزِّلُ قَالُوٓاْ إِنَّمَآ أَنتَ مُفۡتَرِۭۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Nígbà tí A bá pààrọ̀ āyah kan sí àyè āyah kan, Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tó ń sọ̀kalẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kàn jẹ́ aládapa irọ́ ni.” Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
قُلۡ نَزَّلَهُۥ رُوحُ ٱلۡقُدُسِ مِن رَّبِّكَ بِٱلۡحَقِّ لِيُثَبِّتَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُسۡلِمِينَ
Sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ló sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ pẹ̀lú òdodo nítorí kí ó lè mú ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ lódodo rinlẹ̀. (Kí ó sì lè jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَقَدۡ نَعۡلَمُ أَنَّهُمۡ يَقُولُونَ إِنَّمَا يُعَلِّمُهُۥ بَشَرٞۗ لِّسَانُ ٱلَّذِي يُلۡحِدُونَ إِلَيۡهِ أَعۡجَمِيّٞ وَهَٰذَا لِسَانٌ عَرَبِيّٞ مُّبِينٌ
A sì kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: “Ṣebí abara kan ló ń kọ́ ọ (ní al-Ƙur’ān).” Èdè ẹni tí wọ́n ń darí al-Ƙur’ān kọ ní ọ̀nà òdì (pé ó ń kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe elédè Lárúbáwá. Èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé sì ni (al-Ƙur’ān) yìí.[1]
[1] Ẹ wo sūrah al-’Ani‘ām; 6:105.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَا يَهۡدِيهِمُ ٱللَّهُ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Dájúdájú àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, Allāhu kò níí tọ́ wọn sọ́nà. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّمَا يَفۡتَرِي ٱلۡكَذِبَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَٰذِبُونَ
Àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu ló ń dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu). Àwọn wọ̀nyẹn gan-an sì ni òpùrọ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
مَن كَفَرَ بِٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ إِيمَٰنِهِۦٓ إِلَّا مَنۡ أُكۡرِهَ وَقَلۡبُهُۥ مُطۡمَئِنُّۢ بِٱلۡإِيمَٰنِ وَلَٰكِن مَّن شَرَحَ بِٱلۡكُفۡرِ صَدۡرٗا فَعَلَيۡهِمۡ غَضَبٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu lẹ́yìn ìgbàgbọ́ rẹ̀, yàtọ̀ sí ẹni tí wọ́n jẹ nípá, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣí igbá-àyà rẹ̀ sílẹ̀ fún àìgbàgbọ́, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ń bẹ lórí wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ ٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا عَلَى ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Ìyẹn nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju ọ̀run. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ وَسَمۡعِهِمۡ وَأَبۡصَٰرِهِمۡۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡغَٰفِلُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti fi èdídí bo ọkàn wọn, ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni afọ́núfọ́ra.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
لَا جَرَمَ أَنَّهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú àwọn ni olófò ní ọ̀run.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ هَاجَرُواْ مِنۢ بَعۡدِ مَا فُتِنُواْ ثُمَّ جَٰهَدُواْ وَصَبَرُوٓاْ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعۡدِهَا لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti kó ìfòòró bá wọn, lẹ́yìn náà, tí wọ́n jagun ẹ̀sìn, tí wọ́n sì ṣe sùúrù - dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run (fún wọn) lẹ́yìn (ìfòòró tí wọ́n rí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
۞ يَوۡمَ تَأۡتِي كُلُّ نَفۡسٖ تُجَٰدِلُ عَن نَّفۡسِهَا وَتُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
(Rántí) Ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò dé tí yóò máa rojọ́ gbe ara rẹ̀. A ó sì san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́; wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا قَرۡيَةٗ كَانَتۡ ءَامِنَةٗ مُّطۡمَئِنَّةٗ يَأۡتِيهَا رِزۡقُهَا رَغَدٗا مِّن كُلِّ مَكَانٖ فَكَفَرَتۡ بِأَنۡعُمِ ٱللَّهِ فَأَذَٰقَهَا ٱللَّهُ لِبَاسَ ٱلۡجُوعِ وَٱلۡخَوۡفِ بِمَا كَانُواْ يَصۡنَعُونَ
Allāhu fi àkàwé lélẹ̀ nípa ìlú kan, tí ó jẹ́ (ìlú) ààbò àti ìfàyàbalẹ̀, tí arísìkí rẹ̀ ń tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ ní púpọ̀ ní gbogbo àyè. Àmọ́ (wọ́n) ṣe àìmoore sí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ìyà ebi àti ìpáyà tọ́ wò nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَقَدۡ جَآءَهُمۡ رَسُولٞ مِّنۡهُمۡ فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَهُمۡ ظَٰلِمُونَ
Òjíṣẹ́ kúkú ti dé bá wọn láààrin ara wọn. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ọwọ́ ìyà bà wọ́n. Alábòsí sì ni wọ́n.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
فَكُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ حَلَٰلٗا طَيِّبٗا وَٱشۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ
Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín ní n̄ǹkan ẹ̀tọ́, tó dára. Kí ẹ sì dúpẹ́ oore Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةَ وَٱلدَّمَ وَلَحۡمَ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦۖ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fún yín ni ẹran òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tó yàtọ́ sí “Allāhu”. Ṣùgbọ́n ẹni tí ìnira (ebi) bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀), tí kì í ṣe ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَلَا تَقُولُواْ لِمَا تَصِفُ أَلۡسِنَتُكُمُ ٱلۡكَذِبَ هَٰذَا حَلَٰلٞ وَهَٰذَا حَرَامٞ لِّتَفۡتَرُواْ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ لَا يُفۡلِحُونَ
Ẹ má ṣe sọ nípa ohun tí ahọ́n yín ròyìn ní irọ́ pé: “Èyí ni ẹ̀tọ́, èyí sì ni èèwọ̀” nítorí kí ẹ lè dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Dájúdájú àwọn tó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
مَتَٰعٞ قَلِيلٞ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Ìgbádùn ayé bín-íntín (lè wà fún wọn, àmọ́) ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn (ní ọ̀run).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَعَلَى ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا مَا قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ مِن قَبۡلُۖ وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ
Àti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi.[1] A kò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.
[1] Ìyẹn nínú sūrah an-Nisā’; 4:160 - 161.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ عَمِلُواْ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ تَابُواْ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ وَأَصۡلَحُوٓاْ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعۡدِهَا لَغَفُورٞ رَّحِيمٌ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn tó ṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe - lẹ́yìn rẹ̀ (lẹ́yìn ìronú-pìwàdà) dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّ إِبۡرَٰهِيمَ كَانَ أُمَّةٗ قَانِتٗا لِّلَّهِ حَنِيفٗا وَلَمۡ يَكُ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jẹ́ aṣíwájú-àwòkọ́ṣe-rere, olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì jẹ́ ara àwọn ọ̀ṣẹbọ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
شَاكِرٗا لِّأَنۡعُمِهِۚ ٱجۡتَبَىٰهُ وَهَدَىٰهُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Ó máa ń dúpẹ́ àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Allāhu ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَءَاتَيۡنَٰهُ فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗۖ وَإِنَّهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
A ṣe ohun rere fún un nílé ayé. Àti pé ní ọ̀run dájúdájú ó máa wà nínú àwọn ẹni rere.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ثُمَّ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ أَنِ ٱتَّبِعۡ مِلَّةَ إِبۡرَٰهِيمَ حَنِيفٗاۖ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
Lẹ́yìn náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ pé kí o tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì wà lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّمَا جُعِلَ ٱلسَّبۡتُ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِۚ وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ
Àwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀.[1] Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
[1] Yíyapa-ẹnu tí àwọn yẹhudi yapa-ẹnu lórí ṣíṣe àgbéga fún ọjọ́ Jímọ̀, tí wọ́n sì fi ọjọ́ Sabt dípò rẹ̀, l’ó ṣokùnfà bí ọjọ́ náà ṣe di dandan fún ọ̀wọ́ wọn nìkan láti ṣe àgbéga rẹ̀.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
ٱدۡعُ إِلَىٰ سَبِيلِ رَبِّكَ بِٱلۡحِكۡمَةِ وَٱلۡمَوۡعِظَةِ ٱلۡحَسَنَةِۖ وَجَٰدِلۡهُم بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ
Pèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí tó dára jùlọ. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀ (’Islām). Òun l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà (àwọn mùsùlùmí).
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَإِنۡ عَاقَبۡتُمۡ فَعَاقِبُواْ بِمِثۡلِ مَا عُوقِبۡتُم بِهِۦۖ وَلَئِن صَبَرۡتُمۡ لَهُوَ خَيۡرٞ لِّلصَّٰبِرِينَ
Tí ẹ (bá fẹ́) gbẹ̀san (ìyà), ẹ gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣe sùúrù, òhun ló mà lóore jùlọ fún àwọn onísùúrù.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
وَٱصۡبِرۡ وَمَا صَبۡرُكَ إِلَّا بِٱللَّهِۚ وَلَا تَحۡزَنۡ عَلَيۡهِمۡ وَلَا تَكُ فِي ضَيۡقٖ مِّمَّا يَمۡكُرُونَ
Ṣe sùúrù. Ìwọ kò sì lè rí sùúrù ṣe àfi pẹ̀lú (ìrànlọ́wọ́) Allāhu. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì ṣe wà nínú ìbànújẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ń dá ní ète.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّٱلَّذِينَ هُم مُّحۡسِنُونَ
Dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn tó bẹ̀rù (Rẹ̀) àti àwọn tó ń ṣe rere.
ការបកស្រាយជាភាសា​អារ៉ាប់:
 
ការបកប្រែអត្ថន័យ ជំពូក​: អាន់ណះល៍
មាតិកានៃជំពូក លេខ​ទំព័រ
 
ការបកប្រែអត្ថន័យនៃគម្ពីរគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល - មាតិកានៃការបកប្រែ

ការបកប្រែដោយលោក អាពូ​ រ៉ហុីម៉ះ​ មុីកាអុីល​ អៃក្វីនី។

បិទ